OLUWA TI DOJU TI ỌTA, ỌBASANJỌ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, October 7, 2019

OLUWA TI DOJU TI ỌTA, ỌBASANJỌ PARIWO SITA

Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe bi ki i ba a ṣe pe Ọlọrun duro ti awọn ni, o ṣee ṣe ki ipinu ọta lori awọn ile ijọsin toun kọ sinu ọgba ile-ikawe Aarẹ, iyẹn Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library (OOPL) ti wa si imuṣẹ.

Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ yi nibi ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti wọn da ṣọọṣi Chapel of Christ the Glorious King silẹ ninu ọgba OOPL naa niluu Abẹokuta, eyi to waye lọjọ Aiku Sande ana.

Ayẹyẹ ọdun kẹwaa naa la gbọ pe o bẹrẹ lọjọ Ẹti, Fraide si ọjọ Sande ana. Nibẹ ni Oloye Ọbasanjọ ti fi idunnu rẹ han lori bi ṣọọṣi naa ṣe n fojoojumọ gbooro sii, to si ni ko si nnkan meji bi ko ṣe oore ọfẹ Ọlọrun.

Ninu ọrọ Aarẹ tẹlẹri naa, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ pe "Bi ile ijọsin yi ṣe n gbooro si lojoojumọ jẹ iyanu ati iwuri. Nigba ti a bẹrẹ kikọ awọn ile ijọsin yi, awọn kan bu ẹnu atẹ luu, nitori pe wọn ko fẹ ka kọ ọ, ṣugbọn ni bayii, o dami loju pe oju yoo ti maa ti wọn bayii.

"Bo ṣe ri fun ṣọọṣi yi naa lo ri fun mọṣalaṣi fawọn eeyan wa ninu ẹsin Islam. O ye mi wi pe awọn eeyan lọna jinjin naa ma n wa a jọsin nibẹ naa pẹluu. Nnkan iwuri ati aritọkasi lo jẹ.

"Lara awọn ileri ati ẹjẹ ti mo ti jẹ si Ọlọrun ni lati kọ awọn ile ijọsin, ki ipolongo iṣẹ Oluwa ati orukọ Jesu le tubọ maa gbooro siwaju sii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI