ỌMỌ YAHOO MẸFA TUN WỌ GAU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, October 4, 2019

ỌMỌ YAHOO MẸFA TUN WỌ GAU L'EKOO

Lọjọ Tọside ana lọwọ ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC tun tẹ awọn ọdọmọkunrin mẹfa kan ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo lọ.

 
Oluwaṣeyi Gabriel Obe, Ọmọjuyigbe Paul, Olubọdun Victor, Alade Amos Ọpẹyẹmi, Harry Osaremesin ati Osaro Aganwonyi la gbọ pe ọwọ te lagbegbe Igando niluu Ekoo latari olobo ti wọn lawọn kan ta awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC naa.

 
Lara awọn nnkan ti a gbọ pe wọn gba lọwọ wọn ni Foonu loriṣiriṣi, ẹrọ kọmputa alagbeeka ati mọto olowo iyebiye.

A gbọ pe ko ni pẹ ti wọn yoo fi foju awọn eeyan bale ẹjọ lati gba idajọ wọn gẹgẹ bo ṣe tọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI