ỌWỌ TẸ AYEDERU PASITỌ DAVID, LO BA N SUNKUN BI ỌMỌ IKOKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, October 2, 2019

ỌWỌ TẸ AYEDERU PASITỌ DAVID, LO BA N SUNKUN BI ỌMỌ IKOKO

Pupọ awọn to ri David Diri lasiko to n sunkun ni wọn fẹẹ le maa ba a sunkun pẹluu nigba ti wọn ko tii mọ iwa to hu, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ, ṣugbọn diẹ lo ku ki wọn danu sun un nigba ti wọn gbọ ọrọ to n tẹnu rẹ jade.

Ogbologbo gbajuẹ ni wọn pe David ti wọn si lawọn obinrin lo fẹran lati maa fi iran eke lu ni jibiti kaakiri orilẹ-ede Naijiria, paapaa niluu Ekoo.

Ṣugbọn nigba tọwọ palaba rẹ maa segi, wọn ni ṣe lo dabi wi pe awọn orogun iya rẹ ni wọn sa sii ko too ṣiṣe lọjọ naa.

Bọwọ ṣe tẹ ni wọn lo n bẹbẹ fun idariji pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ. AWIKONKO gbọ pe bo ba pade obinrin kan loju ọna, yoo sọ pe Ọlọrun ran oun si wọn, to si jẹ o digba to ba gba gbogbo owo ti wọn ni, ko da ti wọn yoo tun ya owo lati ko lee lọwọ ko too na papa bora ki aṣiri ma baa tu.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI