WỌN DUMBU FELIX BI ẸRAN ILEYA LASIKO TAWỌN AKẸKỌỌ N PALẸMỌ AYẸYẸ AṢA WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 4, 2019

WỌN DUMBU FELIX BI ẸRAN ILEYA LASIKO TAWỌN AKẸKỌỌ N PALẸMỌ AYẸYẸ AṢA WỌN

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lọjọ Tọside ana yi nigba ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan deedee bẹrẹ sii yinbọn kaakiri inu ọgba ile ẹkọ fasiti ti ipinlẹ Cross River, iyẹn Cross River University of Technology (CRUTECH) ni nnkan bi aago mẹta kọja iṣẹju mẹsan an.

 
Ohun ti a gbọ ni pe ọsẹ awọn akẹkọọ ni wọn n ṣe lọwọ, ti wọn lawọn akẹkọọ n ṣe iwọde kaakiri inu ọgba ile ẹkọ naa. Asiko ti wọn ni eto naa n dun lọwọ fun ti ipalẹmọ ọjọ Aṣa wọn to fẹẹ waye lonii ni wọn sọ pe iro ibọn n dun lakọ-lakọ.
Loju ẹsẹ ni wọn lawọn akẹkọọ ti wọn wa nitosi ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti olori si n du ori ẹ ki ibọn ma baa ba wọn, ko da, ti wọn lawọn kan dọbalẹ sinu kọta ati loju ọna lati yẹ fun ọta ibọn.

Ṣe la gbọ pe wọn doju ibọn kọ akẹkọọ kan ti wọn pe ni Felix, ẹni ti wọn ni ipele to gbẹyin lo wa, ti yoo si pari lọdun yi titi to fi ku. Ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn pe Felix, ti wọn si lawọn alatako rẹ ni wọn wa a koju rẹ.

Wọn ni bi wọn ṣe yinbọn pa Felix to, wọn ko gbagbọ pe o ti ku, eyi lo mu ki wọn fi ọbẹ dunbu ọrun rẹ bi ẹran Ileya ko too di pe awọn naa ba ẹsẹ wọn sọrọ.

A gbọ pe loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti debẹ, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ. Iwadii ṣi n lọ lọwọ titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI