Ẹ MAA ṢAYẸWO ỌYAN YIN LOOORE-KOORE, ERELU FAYẸMI GBAWỌN OBINRIN LAMỌNRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 22, 2019

Ẹ MAA ṢAYẸWO ỌYAN YIN LOOORE-KOORE, ERELU FAYẸMI GBAWỌN OBINRIN LAMỌNRAN

Iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayẹmi ti gba gbogbo awọn obinrin nipinlẹ naa, paapaa lorilẹ-ede Naijiria lamọnran wipe ki wọn maa jade lọọ ṣayewọ ẹbun ọyan ti Ọlọrun fun wọn lati dẹkun aarun jẹjẹrẹ ọyan.

Ọjọbọ Tọside ana ni Ere Bisi Fayẹmi sọrọ naa nibi eto iwọde ti ipolongo aarun jẹjẹrẹ (Breast Cervical Cancer Awareness Week) nile-ẹkọ ilera (School of Nursing) to waye niluu Ado-Ekiti.

O ni o pọn dandan fawọn obinrin lati maa yẹ ọmu wọn wo loore-koore nitori pe ilera pipe ni oogun ọrọ, ati pe aarun jẹjẹrẹ kii ṣe nnkan teeyan le bo mọ ara.

Nibẹ lo ti sọ pe eto ti wa nilẹ fun gbogbo awọn obinrin kaakiri ipinlẹ naa lati jẹ anfaani ayẹwo ọfẹ tijọba gbe kalẹ naa, tori pe ilera, aabo ẹmi dukia araalu lo jẹ ijọba logun.

Bẹẹ lo sọ pe awọn lo asiko naa lati fi ṣi gbagede "Adunni Olayinka Wellness Centre", nibi tawọn eeyan yoo ti maa ṣayẹwo ara wọn fun ilera pipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI