FAYẸMI ATI FAYỌṢE: ẸKỌ NLA FUN GBOGBO ỌMỌ NAIJIRIA TI WỌN FẸẸ PA ARA WỌN LORI AWỌN OLOṢELU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 18, 2019

FAYẸMI ATI FAYỌṢE: ẸKỌ NLA FUN GBOGBO ỌMỌ NAIJIRIA TI WỌN FẸẸ PA ARA WỌN LORI AWỌN OLOṢELU

Lọjọ Abamẹta {Satide} ọsẹ to kọja yi ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ Gomina ana nipinlẹ naa, Oloye Ayọdele Peter Fayọṣe, eyi to waye nipinlẹ Ekoo.

Latigba ti fọto awọn oloṣelu meji naa tọpọ awọn ọmọ Naijiria n ri gẹgẹ bi ata ati oju nidi oṣelu ti bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi nipa awọn mejeeji, nitori pe ko sẹni to le nigbagbọ wipe eto tabi ayẹyẹ kankan yoo tun pa awọn mejeeji papọ.

Ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe ti ohun to ṣẹlẹ lọdun to kọja nibi idibo to waye nipinlẹ Ekiti, ti Fayọṣe fẹsun oriṣiriṣi kan Gomina Fayẹmi wipe ṣe ni Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC pawọpọ pẹluu ajọ INEC lati yi ibo fun un. 

Image 
Pẹluu idunnu ati ayọ lawọn mejeeji fi pade ara wọn lọjọ naa, to si n ṣe ọpọ awọn eeyan ni kayeefi wipe awọn mejeeji tawọn eeyan ri gẹgẹ ọta yi tun le rẹrin sira wọn.
Image 
Fun awọn ọdọ ti wọn n ṣeku pa ara wọn lori awọn oloṣelu yoowu nitori apoti ibo, tabi ipo kan, asiko re e lati mọ wipe ko si oloṣelu kankan lorilẹ-ede Naijiria gbọdọ tori ẹ ku. Inu idunnu ati ayọ lọpọ awọn oloṣelu Naijiria n wa wipe awọn eeyan n ku nitori wọn.

Image 
Ẹ jẹ ka ronu gidi.
Twitter post by @AriyoAristotle: Rightly predicted.After the 2014 Ekiti Gov Election, I lampooned a fellow in a yahoo group who tried to denigrate Ekiti people for not voting Fayemi. Falana SAN intervened & said Fayose was a bad omen. I told him the duo worked together in 2010 against Oni & will still be back.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI