LẸ́YÌN Ọ̀SẸ̀ KAN TI EDGAL IMOHIMI DI KỌMIṢANA ỌLỌPAA NIPINLẸ OGUN, WỌ́N TÚN GBE E LỌ SÍ AKWA IBOM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 24, 2019

LẸ́YÌN Ọ̀SẸ̀ KAN TI EDGAL IMOHIMI DI KỌMIṢANA ỌLỌPAA NIPINLẸ OGUN, WỌ́N TÚN GBE E LỌ SÍ AKWA IBOM


Ọjọ́ Ajé Mọnde ọ̀sẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ lo tán yí ni Edgal Imohimi de ọ́fíìsì rẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, èyí tó wà lágbègbè Eleweran niluu Abẹ́òkúta.

Nibẹ lo sì ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun pátápátá wípé kí wọn padà sí teṣan tí wọn tí ń ṣíṣẹ nítorí pé atunto àti igbesẹ eto ààbò tuntun yóò bẹ̀rẹ̀, àti pé òun fẹẹ mọ àwọn tó wà lábẹ́ òun. 

Ìyàlẹ́nu lo tún jẹ́ pé bí eto naa ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni àṣẹ min in tún wà láti olú ileeṣẹ ọlọpaa àgbà orilẹ-ede yí pé kí Edgal Imohimi gba ipinlẹ Akwa Ibom lọ, kò sì lọọ di kọmiṣanna tuntun nibẹ. 

Àṣẹ náà gẹ́gẹ́ bo ṣe tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ ṣe sọ, ó ní ki Kenneth Ebrimson tòun jẹ Kọmiṣanna nipinlẹ Akwa Ibom náà gbà ipinlẹ Ogun lọ láti lọọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ nibẹ.

Bẹ ó bá gbàgbé, ọ̀sẹ̀ tó kọjá yí ni atunto de ba ileeṣẹ ọlọpaa làwọn ipinlẹ mélòó kan, tí wọn sì pín àwọn Kọmiṣanna tunthn sáwọn ipinlẹ tí atunto de ba, tó sì jẹ pe lára wọn ni ipinlẹ Ogun àti Akwa Ibom.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI