LỌỌ JÁWỌ́ NÍNÚ ẸJỌ TO Ń LỌ LỌ́WỌ́, KÍ Ó SÌ GBA KÁMÚ - OLÚ ILARO PÀṢẸ FÚN ỌNỌREBU AKINLADE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 23, 2019

LỌỌ JÁWỌ́ NÍNÚ ẸJỌ TO Ń LỌ LỌ́WỌ́, KÍ Ó SÌ GBA KÁMÚ - OLÚ ILARO PÀṢẸ FÚN ỌNỌREBU AKINLADE


Olú Ilaro, Ọba Gbadewọle Kẹhinde Olugbenle tí pàṣẹ fún oludije sípò Gomina nipinlẹ Ogun lábẹ́ asia ẹgbẹ́ òṣèlú Allied Peoples Movement, Ọnọrebu Adekunle Akinlade wípé kò lọọ jawọ ninu ẹjọ to gbe lọ sile ẹjọ agba orilẹ-ede Naijiria (Supreme Court), eyi to fi n tako esi idibo Gomina to gbe Ọmọba Dapọ Abiọdun wọle loṣu kẹta ọdun yi.

Ọba Olugbele lo sọrọ naa lonii nibi ayẹyẹ ọdun Oronna to n lọ lọwọ niluu Ilaro lasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, nibẹ lo ti sọ pe ko fọwọsowọpọ pẹluu ijọba to n lọ lọwọ, ki ifẹ ati alaafia le tubọ jọba.

Kabiyesi, Ọba Olugbenle to n gba ẹnu gbogbo awọn Ọba ilẹ Yewa sọrọ sọ pe niwọn igba ti Ọnọrebu Akinlade ti paddanu nile ẹjọ Tribunal ati ile ẹjọ Kotẹmilọrun niluu Ibadan, ko tun si idi kan ni pato ti yoo tun fi gbe ẹjọ naa lọ si Abuja mọ.

Ọba Alaye ilẹ Yewa naa tun tẹsiwaju wipe oun fẹran Ọnọrebu Akinlade pupọ gẹgẹ bi ọmọ ilẹ Yewa to si tun n ja fitafita fun ẹtọ, ṣugbọn iyẹn ko ni kou ma sọ oju abẹ nikoo gẹgẹ bi ṣe yẹ.

Ayẹyẹ tọdun yi ta a gbọ pe ileeṣẹ Dangote Group ati MTN ṣagbatẹru lo kun fun awọn eeyan jankanjakan bii igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele; Olori awọn oṣiṣẹ Gomina, Alaaji Shuaib Salisu Ọmọyayi; igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Alaaja Salmọt Badru; Oloye Adigun Sọcopau; Oloye Reuben Abati; Ọnọrebu Suraju Adekunbi; Oloye M. A. Ajibola.

Awọn min in ni Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla to jẹ alaga eto tọdun yi, atawọn aṣofin mẹtala lorilẹ-ede Naijiria to tẹle e wa bii Sẹnetọ Ayọ Akinyẹlure, Sẹnetọ Ọpẹyẹmi Bamidele, Adelere Adeyẹmi Oriolowo atbbl.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI