WỌN YAN IYALAJE TUNTUN NILUU ỌLAOTAN, IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 19, 2019

WỌN YAN IYALAJE TUNTUN NILUU ỌLAOTAN, IPINLẸ OGUN

Gbogbo ilu Ọlaotan to wa lopopona Ajẹbo, iyẹn nijọba ibilẹ Ọbafẹmi/Owode ipinlẹ Ogun ni wọn ko le tete gbagbe ọjọ kẹsan an, oṣu kọkanla ọdun 2019 ninu itan lori bi wọn ṣe yan Oloye Arabinrin Comfort Ọladipupọ gẹgẹ bi Iyalaje tuntun fun ilu naa.
Kii ṣe pe Iyalaje nikan ni wọn yan lọjọ naa, ọjọ naa gan an ni wọn yan Oloye Gabriel Obiwunmi gẹgẹ bi Baale tuntun fun ilu Ọlaotan lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ni Baale ana ti lọ sibi ti agba n re.
Lara awọn Oloye tuntun ti wọn lọjọ naa ni Tunde Awolaja gẹgẹ bi Aṣiwaju; Afọlaṣade Ewedairo gẹgẹ bi Iyalode; Ọlalekan Fadare gẹgẹ bi Akinrọgun; David Ọlabamiji gẹgẹ bi Sarumi; Oluṣẹgun Ewedairo gẹgẹ bi Olori Ọdẹ; Ibrahim Adeọṣun gẹgẹ bi Bada.

Awọn yooku ni Festus Ọsawaru ti wọn jẹ Ajagun Nla; Chris Uwaifoh ti wọn fi jẹ Alatunṣe ati Waheed Ọdenikẹ toun jẹ Ọkanlọmọ.
Nigba to n sọrọ lori pataki ti wọn fi yan Arabinrin Comfort Ọladipupọ gẹgẹ bi Iyalaje ilu Ọlaotan, Oloye Obiwunmi sọ pe lara awọn akitiyan obinrin naa nipa idagbasoke ilu lo jẹ kawọn agbaagba panupọ lati fa a kalẹ fun ipo naa, ti ko si ni alatako kankan.

O ni ṣe ni inu gbogbo ilu dun, ti wọn si lawọn nifẹ si Ọladipupọ lati jẹ oye Iyalaje nigba ti wọn kede rẹ, ko da tawọn eeyan ilu naa tun n sọ pe oriire nla ni yoo jẹ fawọn.
Ninu ọrọ Iyalaje tuntun naa, Oloye Comfort Ọladipupọ sọ pe anfaani nla lo jẹ foun pẹlu bi wọn ṣe fi oye naa da oun lọla, ati pe anfaani lati tubọ gbe iṣẹ Oluwa larugẹ nipo naa jẹ.
Baale Ọlaotan ati Iyalaje tuntun
Obinrin naa sọ pe oun ko kọkọ fẹẹ gba oye naa nigba ti wọn lọ oun, ṣugbọn nigba tawọn toun fọrọ lọ sọ pe wọn kii kọ oye lo jẹ koun pinu lati gba a.
O wa a dupẹ lọwọ Ọlọrun, paapaa Baale ilu naa, Oloye Obiwunmi atawọn agbaagba ilu ti wọn fi yan oun fun ipo naa, to si ṣeleri wipe gbogbo akitiyan lati jẹ ki ilu naa tẹsiwaju loun yoo ṣe.

Diẹ re e lara awọn fọto ayẹyẹ naa































No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI