ADUNNI KASSIM DI ALAGA FIDIHẸ FẸGBẸ OṢELU UDP NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, December 2, 2019

ADUNNI KASSIM DI ALAGA FIDIHẸ FẸGBẸ OṢELU UDP NIPINLẸ OGUN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọkan pataki lara awọn oludije sipo Gomina nipinlẹ Ogun lọdun 2019, Oloye Arabinrin Jackie Adunni Kassim ni wọn yan gẹgẹ bi alaga fidihẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party.

Kii ṣe pe wọn dee de yan Oloye (Ọmọwe) Adunni Kassim gẹgẹ bi alaga fidihẹ bi ko ṣe tawọn ipa manigbagbe to ti ko lawujọ, paapaa ti ilọsiwaju ẹgbẹ oṣelu naa kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa lorilẹ-ede Naijiria, Amofin Godson Okoye fọwọ si lọsẹ to kọja yi lo ti paṣẹ pe ki Oloye Adunni Kassim pe ipade apero gbogbo ọmọ ẹgbẹ laarin oọgbọn ọjọ ti wọn bu ọwọ lu iyansipo rẹ lati le mu ki ẹgbẹ oṣelu naa tubọ rinlẹ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI