B'AWỌN ỌKUNRIN BA FẸ IYAWO MEJI, YOO DIN IWA AGBERE KU - STELLA ABA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 2, 2019

B'AWỌN ỌKUNRIN BA FẸ IYAWO MEJI, YOO DIN IWA AGBERE KU - STELLA ABA

Gbajugbaja onkọrin igbagbọ nni, Stella Aba Seal ti pariwo sita wipe ko si nnkan to jẹ ki iwa agbeere ati panṣaga pọ nita lasiko yi bi ko ṣe pe iyawo kan ṣoṣo tawọn ọkunrin n fẹ silẹ lọ, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Stella Aba lo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹluu gbajumọ oniroyin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Becky laipẹ yi, nibẹ lo si ti sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ bi ọkunrin ba fẹ iyawo meji, iyẹn bi wọn ba ti le ṣe dee de laarin awọn iyawo meji naa, ati pe yoo tun din iwa agbere ku lawujọ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe "Bi baale ile ba mọ pe oun ni ojuṣe, ti mo si jẹ iyawo ẹ, to ba loun fẹẹ fẹ iyawo min in le mi, to si ṣetan lati tọju awa mejeeji bakan naa, mi o ni iṣoro kankan pẹluu ẹ.

"Bi ọkunrin tabi baale ile ba mọ pe wipe oun nifẹ obinrin tabi iyawo ẹ to, ṣe awọn nnkan to ba yẹ, ki o si tun igbeyawo ẹ ṣe. Mo maa n gbawọn obinrin lamọnran, paapaa awọn ọlọmọge ti wọn ba sọ pe awọn ni ọrẹkunrin mẹrin si mẹfa latari wipe wọn ko mọ eyi ti yoo daabo bo wọn.

"Ko si nnkan to buru ki ọkunrin fẹ iyawo meji, yoo din agbere laarin ọkunrin ati obinrin ku lawujọ wa ni."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI