ALATẸNUJẸ LỌPỌ AWỌN PASITỌ TO N TẸLE AWỌN OLOṢELU - WOLII ỌLAYIWỌLA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 7, 2019

ALATẸNUJẸ LỌPỌ AWỌN PASITỌ TO N TẸLE AWỌN OLOṢELU - WOLII ỌLAYIWỌLA PARIWO SITA

Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Ọlayiwọla Mercy ti pariwo sita wipe alatẹnujẹ, alagabangebe lọpọ awọn Pasito ti wọn n tẹle awọn oloṣelu, paapaa lasiko ti ipolongo idibo ba ti n bọ.

Wolii Ọlayiwọla lo sọrọ naa laipẹ yi lori fọnran to gbe sita, nibẹ lo si ti sọ pe olokoowo lo pọ ju nidi iṣẹ Oluwa, idi ni yi ti wọn fi n lo anfaani isọji ti wọn n gbe kaakiri lati maa fi polongo ibo fawọn oloṣelu to ba gbe apoti.

Bakan naa lo tun sọ pe ko yẹ ki ẹni to ti gba Jesu gẹgẹ bi Oluwa tun pada sidi iwa buruku to ti fi silẹ mọ, tori pe igbe aye yẹn ko kan Jesu mọ, bi ko ṣe igbe aye tuntun teeyan n gbe pẹluu Jesu lo kan Jesu.

Diẹ ninu awọn ọrọ rẹ re e:


"Nnkan to ba mu ka gba ọrọ Bibeli yi gbọ, a jẹ pe idalare wa fawọn oloṣelu wa naa ni yẹn. Eeyan buruku patapata ni Sakeu (Zaccheus) jẹ, kii ṣeeyan rere, ko si ọna kankan  to gba ṣe atunṣe ninu ẹsẹ Bibeli ti a n ka, tori pe ninu gbogbo owo to ti ji ko naa lo ti fun gbogbo eeyan to lu ni jibiti.

"Bawo leeyan yoo ṣe ji owo ko, ko wa a gba ile iwosan lọ lati san owo gbogbo awọn ti ko ba ri owo ọsibitu san. Owo to fi pawọn kan lẹkun lo n na. Ibẹru lo jẹ fun un wipe Jesu wa sile ẹ lo jẹ ko sọ nnkan to jade lẹnu ẹ. Aṣodun lo n tẹnu ẹ jade. Bi agabagebe ba ti tẹle aimọkan, iwa buburu lo maa jade nibẹ.

"Agabagede ni ko jẹ ki ọpọ awọn Pasitọ gbadun, awọn ni wọn n bu ẹnu atẹ lu ṣọọṣi fawọn oloṣelu pe ko dara lati maa fi polongo ibo, awọn naa ni wọn tun n pada lo ṣọọṣi fi ṣe isọji fawọn oloṣelu. Gbogbo nnkan ti ko dara lawọn n ri, ti wọn si n ṣe awọn nnkan naa.

"Ohun to mu kawọn eeyan sa wa sọdọ wọn lori iwa mimọ ti wọn n polongo naa ni wọn ti bi wo. Ẹ maa ṣakiyesi pe lati bi ọdun meji sẹyin bayii, awọn oloṣelu ni wọn n tẹle kaakiri, isọji ni wọn fi n polongo ibo fawọn oloṣelu bi asiko idibo ba ti n bọ.

"Oloṣelu to ba gbe apoti yoo wa sibi isọji wọn, ti wọn a gbadura fun un. Awa ri wọn bii olokoowo (Business Man). Ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣiṣẹ Oluwa gbọdọ jẹ olotitọ eeyan, tori pe Bibeli sọ fun wa pe 'Jẹ ki Bẹẹni rẹ jẹ bẹẹni, ki Bẹẹkọ si jẹ bẹẹkọ', ohun to ba ti yatọ si eyi, ti eṣu ni.

"Ko si idi kan ni pato teeyan fi gbọdọ sọ pe bayi ni nnkan ri lonii, ko tun ri bẹẹ mọ ni ọla, ṣugbọn tori pe awọn olokoowo ti pọ ju ninu iṣẹ Oluwa ni ko jẹ ki ọpọ awọn eniyan gba wa gbọ, ko yẹ ko ri bẹẹ. Iwa ọdaju patapata gba a si ni.

"Beeyan ba loun ti fi aye oun fun Jesu, ko yẹ ko tun pada sinu ẹṣẹ to ti kọ silẹ mọ, ati wipe igbe aye to kan Jesu ni igbe aye teeyan ni pẹluu Ẹ, igbe aye to o ti gbe tẹlẹ yẹn ko kan Jesu rara. Bi a ba jẹ ki Bibeli ye wa daadaa, a maa rii daju pe awọn ẹlẹtan lo pọ ninu awa ojiṣẹ Ọlọrun. Asiko naa ti wa a to lati ṣile awọn ayederu Pasitọ olokiki pẹluu gbogbo awọn eewọ ti wọn n tu sita."


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI