Ẹgbẹ Fijilante tijọba apapọ, iyẹn Vigilante Group of
Nigeria, ẹka tipinlẹ Ogun; ẹgbẹ́ Ogun State Hunters Association ati Ẹgbẹ́
Ojulalakanfinṣori ti gbe oṣuba kare fun Kọmiṣana ọlọpaa tuntun nipinlẹ naa,
Kenneth Ebrimson fun akitiyan rẹ lati mu iwa ọ̀daràn wa sopin pátápátá.
L'Ọ́jọ́bọ (Tọside) tó kọjá yí ni Kọmiṣana Kenneth
Ebrimson báwọn ileeṣẹ eleto aabo yí ṣèpàdé láti mọ ọna ti wọn yoo gba rán ara
lọ́wọ́, paapaa bi ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun ṣe ń wọlé bọ̀.
Nigba tó ń b'AWIKONKO sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ẹti (Furaide)
àná, Ọ̀gá àgbà ẹgbẹ́ VGN nipinlẹ Ogun, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin sọ pé koriya
ni ipade náà jẹ, torí pé yóò tún ro gbogbo ileeṣẹ eleto aabo lágbára pupọ pẹluu
bí ileeṣẹ ọlọpaa tún ṣe fún wọn ní ifọwọsowọpọ.
Bẹ́ẹ̀ lo sọ pé nínú àwọn igbesẹ tí Ebrimson ń gbé,
pàápàá fún tí ìpàdé tí wọn ṣe, ó ti fi hàn dájú pé ẹni tí kò nii gba igbakugba,
tàbí fi ọ̀rọ̀ eto ààbò ṣeré rárá.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ síwájú, ó sọ pé "Níbi ìpàdé yí ni
Kọmiṣana Kenneth Ebrimson tí gbé oriyin fún wa, àtàwọn ọmọ iya wa yòókù lórí
igbiyanju wá nípa eto ààbò, fún tí ifọwọsowọpọ wá pẹluu wọn.
"Bí ẹ bá wo nnkan ti Kọmiṣana ṣe pẹluu ipade
yi, ẹ máa ṣàkíyèsí pé akíkanjú, ẹni ọwọ, olórí pípé ọkùnrin ni ẹni ti wọn gbe wa fun wa, tori
pe ọna lati rii pe eto aabo gboopọn sii lo n fẹ, ọna tuntun to tun fẹ ni lati
fọwọsowọpọ pẹluu ẹgbẹ Fijilante, ọlọdẹ atawọn VGN yoo jẹ ko tubọ ṣe aṣeyọri to
peregede, nitori pe awa naa ti pinu lọkan ara wa wipe gbogbo nnkan to ba n fẹ
la maa fun un.
“Gbogbo nnkan ti yoo ba si na
wa lati rii pe awọn ọdaran fi ipinlẹ silẹ la maa sa gbogbo ipa wa le lori, kii
ṣe awọn ọdaran nikan, gbogbo awọn to ba n ni erongba lati huwa ọdaran yoo kọwọ
wọn bọ aṣọ. Awa la sunmọ araalu julọ, ti ọrọ agbegbe wa si ye wa yekeyeke.”
Alaga ẹgbẹ Ẹgba-Ọmọ-Liṣabi
Ojulalakanfinṣori Network, Alaaji Bello Alade Muhammed ninu ọrọ to b’AWIKONO sọ
lo ti sọ pe “Ọga ọlọpaa tuntun yi lo ranṣẹ si wa pe ka waa ṣepade papọ, a sọrọ
lori eto aabo, ti wọn si jẹ ko ye wa pe awa la mọ bi agbegbe wa ṣe ri, ti a le
ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati mu alaafia ba ilu, ka si fọwọsowọpọ pẹluu wọn.
“Bo tilẹ jẹ pe a tun ṣi maa ṣe
ipade min in lati jẹ ki wọn mọ awọn iranlọwọ ti awa naa ma nilo lọdọ wọn, sibẹ,
igbesẹ ti ọga ọlọpaa tuntun yi gbe jẹ iwuri, ti mo si rii gẹgẹ bi ẹni to mọ
nnkan to n ṣe. Inu mi dun pupọ fun ipade naa, ti a si ti ṣetan lati bawọn ṣiṣẹ
papọ, ki irọrun le ba gbogbo araalu ati agbegbe ẹ.
Nigba to n sọrọ lori ẹgbẹ wọn,
o ni ọdun 1995 lawọn ti wa, tawọn ti n ṣiṣẹ aabo, “Vigilante Group of Egbaland
lorukọ ti a n jẹ tẹlẹ, ko too di pe a lọọ fi orukọ tuntun silẹ lọdọ ajọ to n
forukọ ileeṣẹ silẹ lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn CAC. Inu ẹgbẹ wa lawọn ẹgbẹ bii
PCRC, VGN, SO-SAFE CORPS ti jade, ti a si n ṣiṣẹ wa bo ṣe yẹ."
Nigba to n sọrọ lori ipalẹmọ
wọn fun ayẹyẹ ọdun keresimesi to n bọ lọna, “Kọmiṣana sọrọ kikun lori asiko taa
wa yi, lori bi a ṣe maa ṣiṣẹ papọ, bo tilẹ jẹ awa naa ti ni eto nile funra wa.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ wipe awọn kan wa ti wọn ko fẹẹ ṣiṣẹ rara, yatọ si ki wọn jale,
ti wọn si fẹẹ wa gbogbo ọna lati ri owo, a ti sọ funfun gbogbo awọn eeyan wipe
ki wọn gbaradi, ti a si ti ṣe oriṣiriṣi idanilẹkọọ fun wọn.
“A ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ niluu
Ọyẹ-Ekiti laipẹ yi ṣẹlẹ nibi, tori ẹ lawa naa ṣe wa ni igbaradi fawọn oniṣẹ
ibi, ti Ọlọrun si n ti wa lẹyin. A ko fẹ ki ọdaran kankan wọ ipinlẹ Ogun wa. Mo
fẹẹ fi dawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun loju wipe wọn le sun ki wọn diju
mejeeji, ati pe awọn naa gbọdọ fi iwa ọdaran to ba n lọ lagbegbe wọn to wa
leti, tori pe iṣẹ aabo, ajọṣe ni fun gbogbo eeyan, ko ṣee da ṣe.”
No comments:
Post a Comment