Kayeefi n'iku ọmọdebinrin, ọmọdun mẹrindilogun kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Fatima Abubakar ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ siṣẹlẹ naa titi dasiko yi lori bi wọn ṣe sọ pe o ko sinu kọnga, to si gbabẹ jẹ ipe Ọlọrun.
Agbegbe Gajaja to wa nijọba ibilẹ Danbata, ipinlẹ Kano niṣẹlẹ naa ti waye l'Ọjọbọ Tọside ana, to si sọ gbogbo mọlẹbi sinu ẹkun ati ipayinkeke.
AWIKONKO gbọ pe omi ni Fatima lọọ pọn nidi kọnga to wa nitosi ile wọn, pẹluu ipalẹmọ igbeyawo ẹ ti wọn n ṣe, ṣadede ni wọn sọ pe ẹsẹ rẹ yọ, to si mu ori wọnu kọnga. Awọn to wa nibẹ lasiko naa la gbọ pe wọn figbe bọnu bi wọn ṣe rii.
Loju ẹsẹ ni wọn ti sare pe awọn gendekunrin to wa nitosi, nigba ti wọn yoo fi gbe e jade, oku ẹ ni wọn gbe jade
Gbogbo awọn ti wọn wa fun ayẹyẹ naa la gbọ pe wọn n wa ẹkun mu titi dasiko yi. Bẹẹ lọpọ awọn to gbọ siṣẹlẹ n sọ pe kii ṣe oju lasan, o ṣee ṣe ko lọwọ aye ninu.
No comments:
Post a Comment