O MA ṢE O, O KU DẸDẸ KI MATILADA KẸKỌỌ GBOYE NI WỌN GUN UN PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 13, 2019

O MA ṢE O, O KU DẸDẸ KI MATILADA KẸKỌỌ GBOYE NI WỌN GUN UN PA

Gbogbo awọn mọlẹbi ati ọrẹ ọdọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Matilda Itonyo Mark lo si wa ninu ibanujẹ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan lori bi wọn ṣe gun un pa mọ inu ile to n gbe, ti wọn ko si tii mọ awọn to ṣiṣẹ naa.

Ẹka ikẹkọọ ofin (Law Dept) ni fasiti ipinlẹ Rivers to wa niluu Port Harcourt la gbọ pe Matilda, ẹni ọdun mẹrinlelogun naa wa.

Ko si nnkan to jẹ ki iku Matilda maa ya awọn eeyan lẹnu bi ko ṣe bi wọn ṣe sọ pe ṣe lawọn to gun un pa kọkọ fipa ba a sun karakara, ko too di pe wọn gbẹmi ẹ.

Ko si nnkan to jẹ ki iku Matilda maa ya awọn eeyan lẹnu bi ko ṣe bi wọn ṣe sọ pe ṣe lawọn to gun un pa kọkọ fipa ba a sun karakara, ko too di pe wọn gbẹmi ẹ sinu ile to n gbe, eyi to wa nitosi Eagle Island

Awọn ti wọn jọ n gbe la gbọ pe wọn ri oku Matilda ninu agbara ẹjẹ, ki wọn too ranṣẹ sawọn ọlọpaa ti wọn pada gbe oku ẹ lọ si mọṣuari.

Bẹẹ la gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ igbesẹ lati mọ awọn to ṣeku pa Matilda.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI