Gbogbo eto lo tí fẹẹ àti báyìí fún ọkàn lára àwọn gbajugbaja olórin ẹ̀mí lorilẹ-ede Nàìjíríà, Akeremale Oluwatobi lati ko àwo orin rẹ tuntun tó pé ní 'Joy and Pleasure' jáde.
Ọjọ́ Àìkú tíì ṣe Sande, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù yí ni eto ayẹyẹ náà yóò wáyé nínú gbọngan ayẹyẹ Pius De Pius tó wà ní Ijeun-Lukosi, lopopona Lẹmẹ, Abẹ́òkúta bere lati aago méjì ọsan.
Àwọn àgbààgbà, olóṣèlú ati ọtọkulu láwùjọ là gbọ pé wọn ń bọ níbi ayẹyẹ yí lọ́jọ́ náà, lára wọn sì ni Oloye Dare Awodele tọpọ mọ sì Uncle D to jẹ alaga ayẹyẹ; Oloye Soji Olumide tòun jẹ bàbà ẹgbẹ́ àti Oloye Arábìnrin Kemi Abudu tòun jẹ ìhà ẹgbẹ́ olorin wọn.
Aṣọ Ankara tí wọn tá ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà fún ọ̀pá mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rún méjì náírà fún ọ̀pá mẹ́rin là gbọ pé àwọn èèyàn yóò fi wọlé lọ́jọ́ náà, táwọn olólùfẹ́ sì ti ń rà aṣọ náà lọpọ yanturu.
AWIKONKO gbọ pé lára àwọn tí yóò tún mú ọjọ́ náà larinrin ni àwọn bíi Ọnọrebu Yusuff Adejojo tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun; Oloye ṣẹsan Okitoro, Agunna ìlú Ifọ; Oloye Adewunmi Oyedere, Ọnọrebu Yọmi Ajijoye àti ASP Ajayi Adekanye tí yóò wá nibẹ.
Àwọn min in tó tún ti ń múra ọjọ́ náà ni Alaaji Jamil Yahaya; Oloye Maxwell Ayinla; Oloye Lekan Akinbọde; Oloye Àbáyọmi Akeremale, Ọnọrebu Gbenga Oludele àtàwọn min in.
No comments:
Post a Comment