NITORI GBESE OWO-IGBEYAWO, IYAWO ILE NA PAPA BORA LẸYIN IGBEYAWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 25, 2019

NITORI GBESE OWO-IGBEYAWO, IYAWO ILE NA PAPA BORA LẸYIN IGBEYAWO

Pupọ awọn ti wọn gbọ si iṣẹlẹ naa nni wọn la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko le tete pa a de nigba ti wọn gbọ pe iyawo tuntun aṣẹṣẹgbe kan na papa bora lẹyin toun ati ọkọ rẹ ṣe igbeyawo alarinrin tan.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, wọn ni kii ṣe pe iyawo ile ti wọn pe orukọ rẹ ni Adebayọ Deborah Olusanya dee de ko gbogbo ẹru salọ, bi ko ṣe ti gbese owo ajọ ti ko din ni miliọnu marun un naira ti wọn loo jẹ, eyi ti kko ri san lo jẹ ko ba ẹsẹ rẹ sọrọ.
Wọn ni pẹluu ẹbẹ ni Deborah tọpọ tun mọ si Tosin fi gba owo ajọ naa lati fi ṣegbeyawo, to si ṣeleri wipe oun yoo da owo naa pada lẹyin ayẹyẹ igbeyawo rẹ, ṣugbọn ti ko da owo naa pada gẹgẹ bi adehun to ṣe.
Ojoojumọ ni wọn sọ pe Tosin n fi ọla-da-ọla fawọn to gba owo lọwọ wọn, tawọn yẹn naa si tun fi ọjọ kun ọjọ to yẹ ko da owo yi pada. Ṣugbọn nigba ti wọn loo rii pe owo naa ti n fẹẹ di iitju foun, lo jẹ ko juba ehoro, ti ko si sẹni to mọ ibi to wa dasiko yi, ṣugbọn ti wọn lawọn ẹbi rẹ to mọ ibi to wa ko jẹwọ fawọ olowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI