AGBAKO NLA: GBAJUMỌ AAFA LU IYAWO Ẹ PA L’ỌJỌ ỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 3, 2020

AGBAKO NLA: GBAJUMỌ AAFA LU IYAWO Ẹ PA L’ỌJỌ ỌDUN

BỌSUN ỌLANIYI, ABEOKUTA

Epe rabandẹ-rabandẹ l'awọn ara agbegbe Ṣoluade to wa ni Ijeun-Titun niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ṣi n gbe baale ile kan, Mutiu Ṣonọla ṣe latari bo ṣe lu iyawo ẹ, Zainab Ṣotayo pa l'ọjọ ọdun Keresimesi to kọja yi.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni kii ṣe akọkọ re e ti Mutiu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) yoo maa lu Zainab, iyawo rẹ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), ṣugbọn ṣe l'ọrọ naa yiwọ l'aarọ ọjọ naa nigba ti wọn sọ pe ounjẹ lo da wahala silẹ l'aarin awọn mejeeji.

AWIKONKO gbọ pe iyawo meji ni Mutiu fẹ, to si jẹ pe Zainab to lu pa yi ni iyawo keji to fẹ si agbegbe Ijeun-Titun, ọmọ kan ṣoṣo la gbọ pe wọn ṣi bi funra wọn ki ọlọjọ too de lojiji. Wọn ni ọdun to kọja ni Mutiu lu Zainab, to si da ẹru rẹ sita, ko too di pe iyẹn ko lo sile awọn obi ẹ.

Ko tii ju oṣu meje lọ ti wọn sọ pe Zainab ti wọn lo n ta ẹwa tutu l'ọja Kutọ pada sile Mutiu t'oun yan iṣẹ gbẹnagbẹna (carpenter) l'aayo, ti wọn si n pada gbe gẹgẹ bii tọkọ-t'iyawo.

L'Ọjọru Wẹside t'iṣẹlẹ buruku yi waye, a gbọ pe n'igba ti wahala naa bẹrẹ l'aarin awọn mejeeji, gbogbo akitiyan ti won l'awọn araale ṣe lati b'awọn pari ẹ ni wọn loo ja si pabo, ṣugbọn l'ojiji l'ọrọ yiwọ nigba ti wọn ni Zainab bẹrẹ sii pokaka iku nilẹ ti Mutiu n luu mọ.

Ere la gbo pe wọn kọkọ pe e, af'igba ti wọn rii pe ọrọ naa ti kọja oju lasan, loju ẹsẹ ni wọn ni Mutiu ti wọn loo gbajumọ daadaa n'idi iṣẹ aafa lagbegbe naa ti yi ohun rẹ pada wipe ko ma binu, oun n baa ṣere ni, ati pe o ti tan ninu oun, ṣugbọn ti aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.

Loju ẹsẹ l'awọn eeyan ti sọ pe ko tete gbe e lọ si ọsibitu ko too di pe o gbabẹ sọda s'ọrun alakeji, eyi lo muu sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye, Abẹokuta fun itoju, nibi ti ẹpa ko ti boro mọ.

B'awọn dọkita ṣe sọ fun Mutiu pe oku lo gbe f'awọn la gbọ pe omije ti bẹrẹ sii da l'oju ẹ, ti wọn ni ṣe ni aagun bo o, l'oju ẹsẹ naa lo si ti ranṣẹ pe awọn obi Zainab lati sọ fun wọn pe ọmọ wọn ti ku, to si jẹ pe n'igba t'awọn yẹn maa fi sare de ọsibitu naa, oku ọmọ wọn ni wọn ba loootọ.

Ọsibitu l'awọn araale ti wọn tẹle Mutiu gbe Zainab de ọsibitu ti n sọ pe awọn bẹẹ titi wipe ko fi silẹ, ṣugbọn ko gbọ, eyi lo jẹ k'awọn obi Zainab mọ pe ṣe ni Mutiu lu ọmọ pa, l'oju ẹsẹ la gbọ pe Baba Zainab ti gba teṣan ọlọpaa Ibara lọ lati lọọ f'ọrọ naa to wọn leti pe ọkọ ọmọ awọn ti luu pa.

Pẹlu ibanujẹ la gbọ pe Mutiu fi gbe oku Zainab lọ si agboole wọn to wa ni Okeyẹkẹ, nitosi Isabo, iyẹn nibi ti iyale ẹ n gbe l'ọdọ awọn mọlẹbi ẹ (Mutiu), lati le jẹ ki wọn mọ ọran toun da. Ko tii ju ogun iṣẹju ti wọn de Okeyẹkẹ yi la gbọ pe awọn ọlọpaa de, ti wọn si muu lọ teṣan wọn lati gb'ọrọ l'ẹnu ẹ.

N'igba ti AWIKONKO yoo fi de ibi iṣẹlẹ naa ni Okeyẹkẹ l'aaarọ ọjọ naa, a gbọ pe ko pe t'awọn ọlọpaa kuro nibẹ la de, to si jẹ pe awọn ti a ba nibẹ kọ lati ba wa s'ọrọ yatọ si iya agba kan to loun ni olori ẹbi Mutiu.

Iya naa, Arabinrin Salimọt sọ pe “Bi ilẹ ṣe mọ l'aaarọ yi, lo pe wipe iyawo oun wa ni ọsibiu jẹnẹra, o n ṣaisan gidi gan, nigba ti a fi maa de bẹ la rii pe Zainab ti ku. Ibi kọ lo n gbe, ṣugbọn iyaale ẹ lo n gbe ibi. Won ti ja nigba kan ri to jẹ pe Zainab ko ẹru ẹ lọ s'ọdọ awọn obi ẹ, igba to ya la lọ sile wọn, ti a si b'awọn pari ẹ, to si ko pada sile.

“Latigba naa la ko ti gburo ija wọn mọ. Kayeefi l'ọrọ yi jẹ fun wa.”

Ninu ọrọ ti Iyaale Mutiu to kọ lati b’AWIKONKO sọrọ n sọ ni pe “Eedi l'ọrọ yi jẹ fun ọkọ mi, kii ṣ'oju lasan. Ẹwọn re o. Mi o de ile ti wọn n gbe yẹn ri, ko jẹ ki n le mọ ibẹ. Ibi l'emi n gbe ni t'emi.”

Nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe loootọ n'iṣẹlẹ naa, ati pe Mutiu ti f'oju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI