KÉRÉSÌMESÌ: ṢỌỌṢI TREASURE HOUSE OF GOD FUN ẸGBẸRUN MÉJÌLÁ ÈÈYÀN LOUNJẸ ỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


https://haxbyq.com/mario?h=waWQiOjExNDYwMDIsInNpZCI6MTE4NDA4MCwid2lkIjo0MjE1NzYsInNyYyI6Mn0=eyJ&si1=&si2=


Wednesday, December 25, 2019

KÉRÉSÌMESÌ: ṢỌỌṢI TREASURE HOUSE OF GOD FUN ẸGBẸRUN MÉJÌLÁ ÈÈYÀN LOUNJẸ ỌDUN


Ara ọ̀tọ̀ ni ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì tọdun 2019 yí gba yọ ní ṣọọṣi Treasure House of God tó wà niluu Abẹ́òkúta pẹ̀lú bí wọn ṣe fún àwọn èèyàn ti ko dín ni ẹgbẹ̀rún méjìlá lounjẹ àti ẹran ọdún lọfẹẹ. 


Ẹni tó dé bẹ lo lè ròyìn, kò dá tó ṣì ń ṣe ọpọ àwọn tó dé bẹ ní kayeefi pẹ̀lú igbesẹ arambara yí. 

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ọdọọdún ni etí yí máa ń wáyé, níbi tí wọn tí ń fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún lounjẹ láti lọọ se e nílé wọn, táwọn èèyàn tó jẹ́ àǹfààní yí àtàwọn tó gbọ́ nípa rẹ sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alákòóso ṣọọṣi náà. 


Ẹgbẹ̀rún merin làwọn tó jẹ́ àǹfààní yí lọ́dún méjì sẹ́yìn, táwọn tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún márùn-ún sí jẹ àǹfààní lọ́dún tó kọjá, ìyẹn 2018, ṣùgbọ́n tí ọdún yí yàtọ̀ pátápátá pẹluu báwọn tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún méjìlá ṣe gba oúnjẹ jíjẹ. 


Gẹ́gẹ́ bí alága eto ayẹyẹ ọlọdọọdun tí wọn pé ní Jesus Feast, Diakoni Káyọ̀dé Ogunjimi ṣe ṣàlàyé nígbà tó ń báwọn oniroyin sọ̀rọ̀ niluu Abẹ́òkúta lásìkò tí eto naa n lọ lọ́wọ́, ó sọ pé ọ̀nà tí Jésù là kalẹ làwọn ń tọ.

O ni ẹlẹẹkẹrin irú ẹ ní eto tọdun yí, tó sì jẹ pe ọdọọdún ni Ọlọ́run ń bùkún fún àwọn èèyàn àti ìjọ rẹ tó ń ṣagbatẹru eto naa lọdọọdun. 


Ó tún ṣàlàyé síwájú sí í pé kii ṣe àwọn Kristẹni nìkan ni wọn jẹ àǹfààní náà, bí kò ṣe gbogbo èèyàn, tó sì jẹ pe lati fi jeere ọkàn wọn sọ́dọ̀ Jésù Kristi làwọn ṣe ń ṣe é.

Bakan naa lo gbawọn ẹlẹ́sin ìgbàgbọ́ àtàwọn ṣọọṣi tó kú lamọran wípé káwọn náà bẹ̀rẹ̀ igbesẹ yí, láti máa fi tán ìṣòro táwọn èèyàn ń koju lásìkò àti lẹyin pọnpọnṣinṣin ọdún. 


Ṣáájú àsìkò yí ni oludasilẹ ṣọọṣi náà, Pasitọ Ṣẹyẹ Ṣẹnfuye gbàdúrà fáwọn èèyàn náà, bẹ́ẹ̀ lo tún ṣèlérí wípé ọdún tó ń bọ̀ yóò tún ju ọdún yí lọ pẹluu ògo Ọlọ́run. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI