Pẹlu bi ariwo iku gbajumọ ọkùnrin oloogun ìbílẹ̀
nni, Alaaji Abdul-Fatai Yusuf, ti gbogbo aye mọ si ỌKỌ OLÓYÚN ṣe n ja
ran-in-ran-in n'ilẹ, ti ariwo ẹkùn iku rẹ si n lọ jakejado orílẹ̀-èdè yii, àwọn
Ọlọpaa ti fi àṣírí bi wọn ṣe pa ọkùnrin naa at'awọn àṣírí ikọkọ to wa nidii rẹ
s'ita l'oni-in.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,
Ọgbẹni Gbenga Fadeyi fi s'ita l'oni-in lo ti jẹ́ ko di mímọ pe, mọto meji ni
Ọkọ Oloyun gbe rin ni ana to pade iku rẹ. O ni, àwọn Ọlọpaa meji ti wọn di
ìhámọ́ra àt'àwọn eeyan mi-in ni wọn kọwọọ rin pẹ̀lú Ọkọ Oloyun.
Àwọn ẹṣọ aabo l'ọna marun-un ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni alukoro
ileeṣẹ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ọkọ Oloyun at'awọn ti wọn jọ rin irin-ajo l'anaa
pade l'oju ọna, to si ni l'ẹyin eyi ni àwọn agbebọn ti wọn farapamọ s'inu igbo
da ìbọn rẹpẹtẹ bo mọto Ọkọ Oloyun ni oju ọ̀nà Igbo-Ọra si Eruwa n'ipinlẹ Ọ̀yọ́.
Gbenga Fadeyi ni, niṣe ni ọ̀tá ìbọn ẹyọọkàn pere ba
Ọkọ Oloyun, to si pa a ki wọn too gbe e de ileewosan. O ni, àwọn Ọlọpaa meji to
tẹle Ọkọ Oloyun gbiyanju lati le àwọn oniṣẹ ibi to ṣíṣẹ yii mu, ṣùgbọ́n ti wọn
raaye salọ.
O fi kun un pe, àṣírí nla kan to so pọ mọ ọ̀rọ̀ iku
ojiji Ọkọ Oloyun ni bi ọkùnrin ọmọ bibi ilu Otu n'ipinlẹ Ọ̀yọ́ naa ṣe ri àwọn
iwe kan ti wọn fi lu jibiti nla ni ọ́fíìsì rẹ to wa l'Ekoo, to si ni niṣe ni
wọn dana sun àwọn iwe naa lati pa àṣírí to tu si Ọkọ Oloyun l'ọ́wọ́ mọ.
Fadeyi ni, Ejo l'ọ́wọ́ ninu nipa bi wọn ṣe dana sun
àwọn iwe àṣírí to tu si Ọkọ Oloyun naa l'ọ́wọ́, to si lo ni nnkan ṣe pẹ̀lú iku
rẹ. Nitori idi eyi, o l'awọn ti n f'ọrọ wa àwọn òṣìṣẹ́ Ọkọ Oloyun kan at'awọn
Ọlọpaa meji to tẹ le e l'ẹnu wo ni eka to n ṣèwádìí ọ̀ràn ni Iyaganku niluu
Ibadan lati mọ bi iku gbajumọ oníṣègùn ìbílẹ̀ naa ṣe jẹ́.
O kadii ọ̀rọ̀ rẹ n'ilẹ pe, Kọmiṣanna Ọlọpaa Ìpínlẹ̀
Ọ̀yọ́, Ọgbẹni Ṣínà Olukolu ti ṣèlérí pe, laipẹ yii l'awọn yoo tu ìṣù de isale
ikoko iku Ọkọ Oloyun. Ìgbàgbọ́ wa pe, wọn yoo sinku Ọkọ Oloyun siluu rẹ, ìyẹn
ilu Otu l'oni-in.
N'igba aye rẹ, gbajumọ oníṣègùn ìbílẹ̀ ni Ọkọ
Oloyun. Oun ni Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ l'órílẹ̀-èdè yii, ìyẹn
Physiotherapists Association Of Nigeria (PAN), koda ọjọ́ Aiku, ìyẹn Sannde
ọtunla yii ni baba naa fẹẹ lọọ ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ́ PAN ẹ̀ka t'ipinlẹ Ondo.
Ọ̀pọ̀ eeyan lo ti ri iwosan lati ọwọ Ọkọ Oloyun
l'ori ìṣòro wọn n'ipasẹ imọ ewe ati egbo to ni. Oun ni Aláṣẹ ati oludari ileeṣẹ
D-Fayus International to n ṣe àwọn egboogi ìbílẹ̀ bii: Fijk Flusher, Pakurumo,
Ko-Gbebe, Pan-Cola, iresi Megato Rice ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yàtọ̀ si eyi, alaaanu ọpọ eeyan ni Ọkọ Oloyun, bẹ́ẹ̀
lo tun jẹ opomulero ọpọ àwọn olorin esin Islam. Ọdọọdún lo maa n ṣ'eto waasi
Ramadaani ni ileeṣẹ Ọkọ Oloyun to wa l'Ekoo nibi to ti maa n fun àwọn eeyan
l'ounjẹ ọ̀fẹ́ ati oogun Fijk ọ̀fẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn gbajumọ Aafaa, paapaa Sheikh
Muyideen Ajani Bello ni wọn sunmọ Ọkọ Oloyun pupọ.
Ọrẹ àwọn oṣere tiata at'awọn Olorin Fuji tun ni Ọkọ
Oloyun, koda to fẹẹ ma si ọdún kan ki Alaaji Wasiu Alabi Pasuma tabi Alaaji
Saheed Oṣupa ma ṣeré fun un. Yàtọ̀ si awọn eyi, ọrẹ àwọn sọrọsọrọ ori redio ati
telifiṣan ni. Gbajumọ sọrọsọrọ nni, Oloye Timothy Agboọla t'ọpọ eeyan mọ si
Ẹrẹkẹ Ni Shop lo sun mọ ọn ju ninu àwọn sọrọsọrọ.
Iku nla ni iku Ọkọ Oloyun jẹ́ fun gbogbo ọmọ Yoruba,
ṣùgbọ́n àwọn ibeere t'ọpọ eeyan ṣi n beere ni pe, o ṣe je Ọkọ Oloyun nikan ni
ìbọn pa ninu àwọn ti wọn jọ rin irin-ajo?
Àwọn wo lo wa l'ẹyin àṣírí iwe jibiti to tu si Ọkọ
Oloyun l'ọ́wọ́ ati bi wọn ṣe dana sun àwọn iwe naa?
Ẹ jẹ ka gbagbọ pe, àwọn Ọlọpaa yoo tu ìṣù de isale
ikoko iku Ọkọ Oloyun gẹ́gẹ́ bi wọn ṣe ṣèlérí, ṣùgbọ́n ohun gbogbo to pamọ l'oju
awa ẹ̀dá, kedere ni n'iwaju Oluwa.
Lati: Yoruba Tooto
No comments:
Post a Comment