AWỌN ỌLỌKADA F'ẸHONU HAN L'EKOO, WỌN L'AWỌN KO NII GBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 31, 2020

AWỌN ỌLỌKADA F'ẸHONU HAN L'EKOO, WỌN L'AWỌN KO NII GBA

Ko s'ẹni to de ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko l'oni Furaide, ti ko mọ pe inu awọn ọlọkada kaakiri ipinlẹ naa ko dun rara pẹlu igbesẹ t'ijọba ipinlẹ naa gbe laipẹ yii wi pe ohun ko fẹẹ ri ọlọkada kankan l'awọn opopona kọọkan n'ipinlẹ naa mọ.

Awọn ọlọkada ti ko din ni ẹgbẹrun kan la gbọ pe wọn ya lọ s'ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, lati fẹhonu han lori aṣẹ tuntun pe, ọna lati ran wọn lọ s'oko n'ijọba t'awọn f'inu tan fẹẹ gbe yii, tori pe yoo pa awọn lara pupọ, ti wọn si ni ṣe ni ki wọn tete wa nnkan si i.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii n'ijọba Eko gbe aṣẹ kalẹ wi pe awọn ko fẹẹ ri ọlọkada kankan, to fi mọ awọn oni maruwa l'awọn ijọba ibilẹ mẹẹdogun kan mọ.

Gbogbo awọn ọlọkada naa la gbọ pe wọn gbe patako ifẹhonu han lati jẹ k'ijọba mọ pe aṣẹ tuntun naa ko ba wọn lara mu, nitori pe ọna kan ṣoṣo t'awọn fi n jẹun n'iyẹn, n'igba t'awọn ko ti ri iṣẹ ijọba ṣe.

Bẹẹ la tun gbọ pe wọn kọ lẹta ifẹhonu han s'ile igbimọ aṣofin lati tun aṣẹ wọn gbe yẹwo ko too pẹ ju, nitori pe ọpọ awọn eeyan ni yoo di alainiṣẹ l'ọwọ, to si ṣee ṣe ki ole tun pọ n'igboro.

N'igba to n ṣ'oju abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa b'awọn ọlọkada wọnyii s'ọrọ, Ọnọrebu Bisi Yusuf to n ṣoju agbegbe Alimọṣọ sọrọ sọ pe ile igbimọ naa yoo ṣepade mi-in lati gbe lẹta ifẹhonu han wọn yẹwo, ti wọn yoo si gbọ abajade laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI