ALAIMỌKAN L'AWỌN OṢIṢẸ VIO TO N LE MỌTO KAAKIRI - TAOFEEK BABALỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, February 1, 2020

ALAIMỌKAN L'AWỌN OṢIṢẸ VIO TO N LE MỌTO KAAKIRI - TAOFEEK BABALỌLA

Ọga agba l’ẹka amuṣẹya fun àjọ to n yẹ iwe ọkọ wo, ìyẹn Vehicle Inspection Office (VIO) n'ipinlẹ Ogun, Onímọ̀-ẹ̀rọ Abimbọla Taofeek Babalọla ti sọ pe iwa aimọkan lo n da pupọ àwọn oṣiṣẹ wọn ti wọn n le awọn awakọ ti ko fẹẹ duro l'oju popona mu, nitori pe imọ igbalode ti wa lati mu awakọ to ba ṣẹ s’ofin irinna nirorun ti wa.

Onimọ-ẹrọ Taofeek Babalọla lo yanna-naa ọrọ yii f’AWIKONKO laipẹ yìí n'iluu Abẹ́òkúta, nibẹ lo si ti sọ pe oríṣiríṣi eto idanilẹkọọ l’awọn ti ṣètò o silẹ f’awọn awakọ l’ọdun yii, eyi to loo yàtọ̀ sí àwọn ọdún to ti kọjá lọ.

Babalọla sọ pe l’ọpọ igba l’awọn ti d’awọn oṣiṣẹ wọn l’ẹkọọ pe bi wọn ba da mọto duro l'oju popona, ti awakọ naa ko si dúró fún wọn, ohun to yẹ ki wọn ṣe ni lati kọ nọ́mbà irú mọto bẹẹ silẹ, ki wọn si loo yẹ ẹ wo ni ọ́fíìsì lati mọ ẹni to nii, ati adirẹẹsi iru ẹni bẹ́ẹ̀.

O ni eyi ko ni i fa ijamba l'oju popona debi pe ẹ̀mí tabi dukia n ṣòfò danu l'asiko ti wọn ba b’awọn awakọ wọya ija ere sisa loju popona. Babalọla jẹ́ ko di mímọ pe loore-koore t’awọn n ṣé idanilẹkọọ yii ti din iku ojiji ku l'opopona, t’awọn sì ti f’oju ọpọ awakọ to ṣẹ s'ofin ba’le-ẹjọ.

Ninu ọ̀rọ̀ re lọ tun ti sọ pe “A ti n sọ f’awọn oṣiṣẹ wa l’ọpọ igba pe ẹ̀mí ko laarọ, bi wọn ba ri àwọn kọlọrọsi awakọ ti wọn da duro, ṣùgbọ́n ti wọn ko duro fun wọn, ki wọn kọ nọ́mbà idanimọ mọto yẹn silẹ, ki wọn si muu wa si ọ́fíìsì, ibẹ lati maa yẹ mọto naa wo, ti a si maa ri ẹni to ni i lori ẹ̀rọ kọmputa wa, dipo ki wọn maa le wọn, tabi pe ki wọn duro siwaju mọto.

“Ọna igbalode lati mu àwọn awakọ ti wa to si jẹ pe ọpọ àwọn awakọ lati lọọ gbe n'ile wọn, ti wọn si ti f’oju ba’le-ẹjọ. L'ọ́dọọdún la maa n gb’awọn awakọ, paapaa l’awọn garaaji kaakiri Ìpínlẹ̀ Ogun lamọnran wi pe k’awọn naa rọra maa sare l'oju popona, ki wọn si ranti àwọn mọ̀lẹ́bí ti wọn fi silẹ n'ile.

“Èrè wo lo wa ninu k’ẹni to wọ'nu mọto wọn padanu ẹ̀mí ẹ si wọn l’ọwọ. Lara àwọn eto to wa n' ilẹ f’ọdun yii ni pe ọ̀nà ti a fẹẹ gbe idanilẹkọọ gba yàtọ̀ s’awọn ọdún to ku, ati pe àwọn to n wọ mọto naa yoo tun gba idanilẹkọọ l’ọdun yii, fun aabo ẹ̀mí ati dukia onikaluku ni.”

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI