IKUNLẸ ABIYAMỌ O: WỌN NI KEITA, GBAJUGBAJA AGBABỌỌLU LIVERPOOL TI KO AARUN CORONAVIRUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, January 31, 2020

IKUNLẸ ABIYAMỌ O: WỌN NI KEITA, GBAJUGBAJA AGBABỌỌLU LIVERPOOL TI KO AARUN CORONAVIRUS

Bi awuyewuye to tẹ AWIKONKO l'ọwọ laipẹ yii ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afi ki gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri agbaye mura s'ọrọ ara wọn gidigidi l'asiko yii, lori bi wọn ṣe sọ pe agbabọọlu ti ogo ati irawọ rẹ n tan gidi lasiko yii, Naby Keita ṣe ti ko aarun aṣkupani kan ti wọn pe ni Coronavirus, eyi t'awọn dokita l'awọn ko tii ri ọna abayọ si i.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le f'idi iroyin naa mulẹ boya otitọ ni, ṣugbọn ori ikanni ayelujara ti Twitter to jẹ ti @Spectatorindex la ti ri iroyin naa wi pe ọmọ orilẹ-ede Guinea to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ti ni aarun naa, t'awọn eeyan si ti bẹrẹ si i sọ oriṣiriṣi n'ipa ẹ.

Adura t'awọn ololufẹ Keita n gba bayii ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki iroyin naa jẹ otitọ, nitori ti wọn ko fẹẹ padanu ẹ l'asiko yii, nitori pe ọkan pataki l'ara awọn to n gbe ogo ilẹ adulawọ larugẹ n'idi bọọlu ni.

Spectatorindex:“BREAKING: Liverpool Football Club Midfielder Naby Keita is the first person in the United Kingdom confirmed to have contracted the coronavirus” Meanwhile, further investigation revealed that Naby Keita is currently receiving treatment in an isolated hospital in united kingdom.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI