WỌN NI MỌTO ILEEṢẸ NLA KAN N JONA L'ỌWỌ NI RIDIIMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, January 31, 2020

WỌN NI MỌTO ILEEṢẸ NLA KAN N JONA L'ỌWỌ NI RIDIIMU

Ileeṣẹ to n ri si ijageere opopona n'ipinlẹ Ogun, iyẹn TRACE ti jẹ ko di mimọ pe mọto ileeṣẹ kan to n ṣe opopona, iyẹn Buildwell ti gbina, to si ti fẹẹ jona di eeru l'asiko ta a fi ko iroyin yii jọ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le f'idi nnkan to fa ijamba ina naa lelẹ, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe lojiji lo gbana lori iṣẹ, to si ko ibẹrubojo s'ọkan eeyan.

Iwaju ṣọọṣi awọn ọdọ ti ijọ Ridiimu to jẹ ti Baba Adeboye, iyẹn Redeemed Youth Camp to wa loju ọna Eko siluu Ibadan n'iṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yii, ti a si gbọ pe l'oju ẹsẹ l'awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti de bẹ lati pa ina naa.

AWIKONKO gbọ pe ọwọ ti mọto nla naa ti wọn pe ni 30 tone crane fi n jona kọja sisọ, ti ko si ṣee ṣe k'awọn ileeṣẹ panapana ri ina naa da duro.

Alukoro ileeṣẹ TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi to f'iṣẹlẹ naa to wa leti gb'awọn awakọ lamọnran wi pe ki wọn ṣe jẹjẹ l'oju ọna naa, bo tilẹ pe o l'awọn oṣiṣẹ wọn ti wa n'ibẹ lati wo bi nnkan ṣe n lọ si i.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI