AFIGBA TI MERCY AIGBE TẸ PO O: WỌN NI IWA AGBERE LO LEE KURO N'ILE ỌKỌ RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 16, 2020

AFIGBA TI MERCY AIGBE TẸ PO O: WỌN NI IWA AGBERE LO LEE KURO N'ILE ỌKỌ RẸ

Laipẹ yii ni awọn eeyan bẹrẹ si ni da ẹnu bo gbajugba oṣere fiimu Yoruba, Mercy Aigbe lori ọrọ to sọ lori akanṣe eto kan to ṣe ni ayajọ ọjọ awọn ololufẹ.

Titi di asiko yii, ọrọ naa ko tii tan nilẹ tori ṣe ni ọpọ eniyan n ta abuku ba apa kan ọrọ ti o sọ, bẹẹ naa ni awọn to n kan sara si i naa n gboriyin fun un.

Eto naa lo da lori ọrọ imọran fun awọn eeyan lọjọ ayajọ ololufẹ ti gbogbo eniyan n pe ni Valentine.

Lẹyin to gba awọn iyawo ile nimọran tiwọn tan lori ọna ati mu ọkọ wọn mọlẹ ko ma lee jade layajọ ọjọ ololufẹ naa lo da ẹnu le ohun to yẹ ki awọn ọlọmọge ṣe.


"Ẹyin ọmọge to n fẹ baale ile, o ti baba buru pe o n fẹ baale ile nitori naa o jẹ tete maa gba owo lọwọ ẹ. Ri i pe o wa nidi apo rẹ gbagba".

Esi si Mercy Aigbe 
Mercy ni beeyan ba tilẹ fẹ jẹ ọpọlọ, ko jẹ eyi to lẹyin ninu "tori ọkunrin yẹn kii ṣe tiẹ tẹlẹ, obinrin mii lo ni i. koo yaa tete maa ka a lọwọ rẹ.

Boo ba mọ pe o n fẹ ọkunrin to ti niyawo nile, ma jẹ ki ifẹ bo ẹ loju ma lọ maa gba Shokoleeti ati ododo, gba awọn nkan nla nla bii ọkọ bii Benz, ile ati bẹẹ bẹẹ lọ".

Awọn eeyan ko jẹ ko tutu rara:


Ayo Lawal (@ayolifecode) ni eyi fi lo fihan pe o yẹ ki ẹ ṣọra fun iru awọn tẹ o maa gb ọ̀rọ̀ ti yoo wọ yin lori. "Pe oju opo eeyan daju ko tumọ si pe ọpọlọ ẹni bẹẹ daju o".


DaddyMo(@therealdaddymo1) naa ni "ẹni ti ẹ pe ni awokọṣe yin ree o to n gba awọn obinrin niyanju lati maa ka owo jade nigba ti wọn ba n fẹ ọkunrin to ti niyawo nile".

Bakan naa loju opo instagram rẹ wọn tun ya debẹ pe "mo bọwọ fun ẹ gan o. Ṣugbọn ile melo lo fẹ tu ka lonii...". thegr8_teejay lo sọ bẹẹ.


smart_vicktor ni tirẹ ni ase rọ gbaa lo n sọ nigba ti mkr_kiddies pariwo pe "Mercy ti tu aṣiri ọrọ jade o!".

Mercy ni nkan to le mu ki ọkunrin to niyawo to ni ọmọ nile ni ojukokoro maa gbe ọmọge kiri, o yẹ ki gbogbo awọn ọmọge para pọ ki wọn gbọn ọn gbẹ ki ori rẹ le pe.


"Ni tirẹ, ẹ lee ra awọtẹlẹ oke ati tisalẹ fun un. Ṣugbọn ẹyin ọmọge, ẹ ma lọ maa gba nkan pẹpẹpẹ lọwọ baba alaanu yin o, ri i pe tori nkan ti waa ri gba nibẹ lo fi n fẹ ẹ́".

Kii kuku ṣe awọn abilekọ ati ọmọge nikan lo fi eto rẹ gba nimọran, awọn ọdọ to ṣi ni ibale wọn, awọn ọkunrin ti ko lee pa abẹ wọn mọ, ki wọn lo rọba idaabo bo bi bẹẹ kọ to ba di oyun mọ wọn lọwọ, ki wọn rii pe wọ́n ṣe ojuṣe wọn.

Awọn to gba tirẹ naa ko kọ rara lati kan sara si i fun iṣẹ ti o ṣe ati bi o ṣe wu wọn ori to pẹlu rẹ rẹ. Bi awọn kan ṣe n dupẹ lọwọ rẹ fun imọran bẹẹ lawọn mii n kan sara si isọwọ ṣe awada rẹ.

Shoxzy tilẹ ni ọpọ eeyan lee ro pe ọrọ rẹ ko mu ọgbọn wa ṣugbọn ootọ to koro ni. Ninu abala eto naa ti oun ti kọgbọn, o ni ko yẹ ki ifẹ jẹ ọrọ ọjọ kan pere ṣugbọn ko tun pọ sii lọjọ ayẹyẹ Falantain ni.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI