Ṣe ni ṣọọṣi kan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ bayii daru n'igba ti wọn l'awọn ọmọ ijọ fariga wi pe awọn gbọdọ gba gbogbo owo ọrẹ ati idamẹwaa t'awọn ti n da lati ọdun meloo kan sẹyin.
Ko si nnkan meji to mu k'awọn ọmọ ijọ naa fa ibinu yọ si pasitọ wọn, bi ko ṣe ti mọto tuntun ti wọn ni pasitọ naa ṣẹṣẹ ra, iyẹn Range Rover ti wọn l'owo ẹ ko din ni ogun miliọnu owo naira.
Orilẹ-ede Ghana la gbọ pe iṣẹlẹ yi ti waye l'oṣu kejila ọdun to kọja, 2019, ti ọrọ naa ko si ti i tan n'ilẹ latigba naa.
AWIKONKO gbọ pe ohun to mu k'awọn ọmọ ijọ naa maa binu si pasitọ wọn ni pe owo idamẹwaa lo maa n tẹnumọ ni gbogbo ọjọ Sannde wi pe dandan ni, ko da, ti wọn loo tun maa n darukọ awọn ti wọn ki i san idamẹwaa wọn deede lori pẹpẹ.
Bẹẹ ni wọn sọ pe ko si iranlọwọ ti wọn le ba de iwaju pasitọ ti yoo ṣe e fun wọn, wọn ni ki i ran awọn alaini, tabi awọn ti ebi ba n pa l'ọwọ, to si maa n sọ pe ko si owo l'ọwọ oun.
Awuyewuye naa ti n lọ n'igba ti pasitọ yii ra mọto naa, t'awọn kan si n sọ pe ko le ri bẹẹ. Ṣugbọn l'ọjọ t'iṣẹlẹ naa waye, iyẹn l'ọjọ t'ọrọ naa di iṣu ata yanyan-an, wọn ni awọn ọmọ ijọ naa gbọ pe pasitọ yii fẹ ẹ de ẹka ileeṣẹ ijọba, ti wọn si mura lọọ ba a nibẹ lati boya otitọ ni.
Bi wọn ṣe ri mọto naa to wọnu ọgba la gbọ pe wọn ti sare lọ sibẹ lati wo ẹni to wa nibẹ, to si jẹ iyalẹnu wi pe pasito ati iyawo ẹ ni wọn wa ninu ẹ, ti wọn si ni ko n'iṣẹ kankan l'ọwọ yatọ si iṣẹ pasitọ.
No comments:
Post a Comment