Wọn ní àdúrà lo ń gba, agbára kọ. Èyí gan án lo lọ n'ibamu pẹ̀lú bí ọwọ àwọn ọlọpaa ṣe tẹ gendekunrin kan tí ìgbàgbọ́ wá pé ọkàn lára àwọn Boko Haram aṣekupani ni.
Ọkàn lára àwọn ṣọọṣi Pasitọ David Oyedepo to ni Living Faith Church káàkiri àgbáyé, èyí tó wà n'ilu Kaduna là gbọ pé wọn tí mú gendekunrin náà tí wọn lásìkò tó fẹẹ ju bọnbu silẹ.
A gbọ pé àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé kan tí wọn fí ń ṣàyẹ̀wò ìbọn àti bọnbu lára àwọn èèyàn ló tú àṣírí gendekunrin yìí sáwọn ọlọpaa lọ́wọ́.
Ariwo "Praise The Lord" lo gba ẹnu àwọn ọmọ ìjọ náà nígbà tí àṣírí gendekunrin yìí tú loni-ín Sannde.
No comments:
Post a Comment