O PARI SHEIKH MUYIDEEN BELLO TU ÀṢÍRÍ NLA NÍPA ỌKỌ OLOYUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 2, 2020

O PARI SHEIKH MUYIDEEN BELLO TU ÀṢÍRÍ NLA NÍPA ỌKỌ OLOYUN


O sọ nnkan nla to n mura ko too ku

Ni ana ọjọ́ Abamẹta, ìyẹn Satide ti wọn ṣ'adura fun gbajumọ Dọkita iṣegun ìbílẹ̀ nni, Alaaji Fatai Yusuf t'ọpọ eeyan mọ si Ọkọ Oloyun ni ile igbafẹ rẹ, ìyẹn Fun City to wa l'agbegbe Igando n'ipinlẹ Eko ni gbajumọ oniwaasi agbaye nni, Sheikh Muyideen Bello tu aṣiri nla nipa ohun ti Ọkọ Oloyun n mura ki wọn to pa a.

Sheikh Muyideen Bello ni, Ọkọ Oloyun n kọ orúkọ àwọn Musulumi to fẹẹ ran ni aaji (hajj) l'órílẹ̀-èdè Saudi Arabia l'ọdun yii l'ọ́wọ́ ni iku wọlé de fun un. O ni, alaaanu nla ti ọpọ eeyan ko le gbagbe ni Ọkọ Oloyun.


Agba Aafaa yii ni, pẹ̀lú bo se jẹ musulumi ododo to, ṣe lo tun maa n ran àwọn kirisitẹẹni ni Jerúsálẹ́mù l'ọdọọdun.

Eyi nikan kọ o, o ni Ọkọ Oloyun tun maa n sanwo ileewe ọpọ eeyan ti ko mọ ri rara. Nipa àwọn to jẹ Ọkọ Oloyun ni gbese àt'àwọn onibaara ti wọn f'owo d'oko-owo s'ogun-d'ogoji Option C n'ibi t'áwọn eeyan yoo ti gba idamẹwaa owo wọn l'ẹyin asiko díẹ̀ n'ileeṣẹ Oloogbe, Sheikh Muyideen Bello ni, ọrọ naa maa yanju.


O ni, "Gbara t'iroyin iku Ọkọ Oloyun ti jade l'awọn ti wọn jẹ ẹ ni gbese ti n dunnu pe, àwọn ti jẹ owo rẹ gbe. Bi ẹ ko ba tete san gbese naa, o maa gba a pada l'ọ́wọ́ yin l'ọ́jọ́ igbedide alukiyaamọ. Ninu irun wakati marun-un yin at'awọn iṣẹ ire yin ni wọn ti maa san gbese naa ni alukiyaamọ nitori b'eeyan ba ku pẹ̀lú gbese l'ọrun, yoo san an dandan ni ọrùn ni.

"Nipa ẹyin ti ẹ f'owo d'oko-owo n'ileeṣẹ Ọkọ Oloyun, mo bẹ yin pe ki ẹ ni suuru. Ẹ maa gba owo yin. Ẹ kuku ri i pe, Ọkọ Oloyun ti ku, bẹ́ẹ̀ ni ko mu owo kankan lọ s'ọrun. Ile aye ta a wa yii naa ni gbogbo owo yin wa. Mo n'igbagbọ pe, àwọn ẹbí at'awọn alaṣẹ ileeṣẹ rẹ yoo san gbese naa laipẹ.

"Ni ti ileeṣẹ Ọkọ Oloyun at'awọn iṣẹ ọwọ rẹ, mo bẹ ẹyin ẹbi ati ẹyin òṣìṣẹ́ lati tun ara mu, ki ẹ má ṣe jẹ k'ileeṣẹ rẹ parun l'ẹyin rẹ o. Gbogbo àwọn ìṣẹ ọwọ rẹ ni ki ẹ jẹ ko maa f'ọhun nìṣó. Bo tilẹ̀ jẹ́ pe Ọkọ Oloyun ti ku, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ ọwọ rẹ , paapaa àwọn oogun iwosan to ṣe ṣi n f'ọhun."


Diẹ l'ara oye ti Ọkọ Oloyun jẹ́ n'igba to wa l'aye ni: Ààrẹ Adinni ẹgbẹ́ àwọn Imaamu ati Aafaa ẹ̀ka ti Alimọṣọ l'Ekoo, Ààrẹ Fiwajoye t'ilu Egbe n'ipinlẹ Eko, Ààrẹ Mayegun ilu Igando l'Ekoo, Ààrẹ Apagunpọtẹ-Arun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú ìwọ oorun ilẹ̀ adulawo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI