AWỌN AGBẸ ONI-KOKO Ṣ'ABẸWO SI KỌMIṢANNA F'ETO IṢẸ AGBẸ N'IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 29, 2020

AWỌN AGBẸ ONI-KOKO Ṣ'ABẸWO SI KỌMIṢANNA F'ETO IṢẸ AGBẸ N'IPINLẸ OGUN

Ọjọ Ajẹ ti i ṣe Mọnde to kọja yii l'awọn agbẹ oni-koko (Cocoa) ti wọn wa lagbegbe J4 n'ipinlẹ Ogun ṣe abẹwo si ọfiisi Kọmiṣanna f'eto agbẹ n'ipinlẹ naa, iyẹn Ọmọwe Adeọla Ọdẹdina to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta lati wa ni irẹpọ.

N'ibi abẹwo naa ni wọn ti f'ọkan ijọba ipinlẹ Ogun, paapaa Kọmiṣanna naa balẹ wi pe awọn wa lẹyin rẹ digbi, t'awọn si ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹ fun idagbasoke iṣẹ agbẹ ati ọgbin.

Wọn gbogbo awọn ọna ti yo mu idagbasoke ba eto agbẹ n'ipinlẹ Ogun, paapaa lọna igbalode l'awọn ti ṣetan fi ran ijọba lọwọ.

Lara awọn ti wọn tun wa n'ibi abẹwo ti wọn ti f'ẹmi imoore han ni Akọwe agba l'ẹka iṣẹ agbẹ, Ọmọwe Dọtun Ṣorunkẹ; Oludamọran fun Gomina lori eto iṣẹ agbẹ, Ọmọwe Angel Adelaja-Kuyẹ atawọn mi-in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI