IKUNLẸ ABIYAMỌ O! WỌN DA ẸJỌ IKU FUN IBRAHIM ATI ABASS NITORI ẸSUN KOKEENI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 29, 2020

IKUNLẸ ABIYAMỌ O! WỌN DA ẸJỌ IKU FUN IBRAHIM ATI ABASS NITORI ẸSUN KOKEENI

Kani awọn ọdọmọkunrin meji ti wọn fi Naijiri silẹ wa iṣẹ aje lọ si India mọ pe iku ni yoo gbẹyin wọn, boya wọn ko ba ti wa iṣẹ mi-in ti yoo lowo lori daadaa ju kokeeni lọ ṣe.

Ibrahim ọmọdunmọkandinlọgbọn la gbọ pe ilu Ajaro lorilẹ-ede Naijiria lo ti kuro lọ si India l'ọdun 2016 lati kẹkọọ siwaju si i, ṣugbọn to jẹ pe lojiji lo sọ pe oun ko kawe mọ, ti ko si sẹni to le sọ idi pataki to fi gbe igbesẹ naa.

Abass t'oun jẹ ọmọdun mẹtalelogun la gbọ pe ilu Kano loun ti kuro l'ọdun 2015 lọ si India lati lọ kẹkọọ, to si jẹ pe ọdun to kọja lo kẹkọọ-gboye imọ B.Sc n'idi iṣẹ ogun (medicine).
 
Ko pẹ l'awọn mejeeji pade ara wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ta kokeeni, eyi to lodi si ofin India ko to o di pe aṣiri wọn tu sita.
 
Kokeeni ti iwọn rẹ gbe giraamu mọkanlelogun (21grams) la gbọ pe wọn ka mọ wọn lọwọ ni Apex circle to wa ni Maviya, Nagar orilẹ-ede India, ti wọn si f'oju wọn bale-ẹjọ.

Ohun to ya ni lẹnu ni pe idajọ iku ni wọn ri gba lẹyin ti gbogbo ẹbẹ wọn fori ṣanpọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI