AWỌN ỌLỌPAA N WA DỌLAPỌ TO LU ONIROYIN NI JIBITI L’AKURẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 11, 2020

AWỌN ỌLỌPAA N WA DỌLAPỌ TO LU ONIROYIN NI JIBITI L’AKURẸ

Titi d’asiko ti a fi ko iroyin yii jọ tan l’awọn ọlọpaa ṣi n wa gendekunrin kan t’ọjọ ori ẹ ko ti i ju ọdun mejilelogun lọ, iyẹn Dọlapọ James Ọlaniran ti wọn loo lu oniroyin kan, Ọgbẹni Awoyẹmi Ọlayinka ni jibiti owo, to si salọ.

Iduna-dura kan la gbọ pe o waye laaarin Dọlapọ ati Ọlayinka, ti wọn si ni bi Dọlapọ ṣe gba owo tan, ṣe lo ba ẹsẹ rẹ sọrọ.

Ki i ṣe pe wọn ni Dọlapọ na papa bora nikan, wọn ni ṣe lo tun n dunkooko mọ Ọlayinka wi pe ko gbọdọ pe oun tabi fi atẹjiṣẹ ranṣẹ s’oun mọ bi ko ba fẹ ẹ ri wahala.

Idi ni yii ti wọn ni Ọlayinka fi gba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ati ọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ, lati fi ọrọ naa to wọn leti, ti wọn si l’awọn ọlọpaa ti n wa gbogbo ọna lati ri Dọlapọ mu.

Banki FCMB la gbọ pe Dọlapọ fi lu jibiti, ti wọn si ni gbara ti owo naa ti wọle ni wọn ko ti gburo rẹ mọ titi di asiko yii.

Account Name: Olaniran James Dolapo
Account Number: 6326788012
Bank: FCMB

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI