L'ọjọ Sannde ijẹta yii l'ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ gbogboniṣe to wa n'ilu Ilaro, iyẹn Ilaro Poly n'ibi ti wọn l'oun at'awọn akẹgbẹ rẹ ti nn ṣ'ẹgbẹ okunkun.
Adegboye Ọlatunji ni wọn pe orukọ rẹ. Ọdun to kọja la gbọ pe awọn akẹkọọ dibo fun un gẹgẹ bi Aarẹ wọn, ati pe ko jẹ agbẹnusọ fun wọn.
A ti ẹ gbọ pe ọpọ igba l'awọn eeyan, paapaa awọn alatako rẹ f'ẹsun kan an wi pe olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti Ayee ni, ṣugbọn ti wọn loo tako ẹsun naa.
Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun to f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe inu igbo nla kan ti wọn pe ni Gbogidi, Ilaro ni ọwọ palaba ẹ ti segi pẹlu igbakeji rẹ, Ọlanrewaju Taiwo.
Ni kete t'iroyin naa ti jade l'awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti sọ pe awọn ti daa duro fun igba diẹ naa, ati pe awọn ko ti i fẹ ri i l'ọgba ile ẹkọ naa l'asiko yii.
No comments:
Post a Comment