Titi di àsìkò tí ẹ ń ka ìròyìn yìí l'ọrọ Arẹ̀wà ọmọge tí wọn làwọn ọmọ Yahoo fi ṣoogun owó lọsẹ tó kọjá yìí ṣí ń jẹ kayeefi f'áwọn tó gbọ.
Agbègbè Ọsọ̀sà tó wà lopopona Ṣagamu sì Ìjẹ̀bú-Ode ni iṣẹlẹ náà tí wáyé lọsẹ tó kọjá yìí.
A gbọ pé nnkan bí aago mẹ́wàá àárọ̀ ọjọ Mọnde ọ̀sẹ̀ tó kọjá l'awọn èèyàn tó wà lágbègbè náà rí mọto jiipu ńlá kan tó dúró sí ẹgbẹ́ òpópónà.
Lójijì ni wọn rí í pé ṣe ni wọn ti arẹwà bọ silẹ nínú mọto náà, tó sì ṣubú silẹ. Àwọn tó wà nibẹ gbìyànjú láti wo àwọn tó wà nínú mọto náà, ṣùgbọ́n kí wọn tó o debẹ, mọto náà ṣì, wọn si salọ.
Nígbà tí wọn máa rí arẹwà yìí, ṣe ló ń ṣe bí í alaaganna. Gbogbo bí wọn ṣe ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni wọn lọ ń sọ katikati lẹ́nu.
Ọkàn lára àwọn tó wà nibẹ là gbọ pé ó mú arẹwà náà lọ sí abẹ igi kan láti túbọ̀ fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wo.
Ìgbà tí wọn rí í pé bákan náà ni ọrọ tó ń sọ lẹ́nu, lo mú kí wọn muu lọ ṣọọṣi kan láti gbàdúrà fún un.
No comments:
Post a Comment