AYỌ ABARA TINTIN! OLORI KEKERE ALAAFIN ỌYỌ BIMỌ TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 17, 2020

AYỌ ABARA TINTIN! OLORI KEKERE ALAAFIN ỌYỌ BIMỌ TUNTUN

Olori kekere ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta ti bi ọmọ ọkunrin tuntun.

Ọmọ tuntun ọhun ni iyawo kabiesi to kere julọ, Olori Damilọla Adeyẹmi bi fun un.

Ninu ọrọ ti Olori naa fi s'oju opo Instagram rẹ lo ti ki ara rẹ ku oriire, to si kọ akọle kan sibẹ pe "Mo ki ara mi ku ori ire, ọmọ ọba ti de."

Ọkan lara awọn ọmọ Alaafin, Bunmi Labiyi fi idi ọrọ naa mulẹ, ko da, ti Alaafin funra rẹ tun gbe e sọri ikanni ayelujara ti Fesibuuku rẹ laarọ oni.

O sọ pe ounjẹ gidi ti Alaafin n jẹ ati awọn ere idaraya to ma n ṣe ṣeeṣe ko jẹ ohun to ṣi n fun baba ni okun bi ọdọmọde.

Bunmi ni "Baba mi ki n ṣaye bi awọn eeyan mii ṣe ma n ṣe aye wọn. Kii jẹ ijẹkujẹ."

Bunmi tẹ siwaju pe Alaafin mọ irufẹ ounjẹ to yẹ ko jẹ ati iru ounjẹ ti ko yẹ ko jẹ, koda o ni Kabiesi kii mu ẹlẹrindodo "Coca Cola."

Bakan naa, o fi hande pe onimọ nipa ounjẹ jijẹ ni Kabiesi to si maa n kilọ fun awọn eeyan nipa iru awọn akanpọ ounjẹ ti wọn n jẹ.


Ọmọ Ọba ṣalaye pe "Baba mi jẹ ẹni to mọ nipa ounjẹ gidi. Kii sọ pe nitori o jẹ Ọba Alaye ko wa maa jẹ ijẹkujẹ ki wọn eeyan le ri pe Alaafin lo n jẹun. Boya idi niyẹn ti Baba ṣi fi ni okun."

O pari ọrọ rẹ pe Kabiesi fẹran ere idaraya to bẹ to fi jẹ pe o loju ọdọmọde to lee figa gbaga pẹlu Alaafin ti wọn ba bẹrẹ si n rin papọ.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI