Ẹ WO OJU AKẸKỌỌ TI WỌN JU S'ẸWỌN ỌDUN MEJE L'ENUGU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 27, 2020

Ẹ WO OJU AKẸKỌỌ TI WỌN JU S'ẸWỌN ỌDUN MEJE L'ENUGU

Ọdun meje gbako ni Cynthia Nwankwo Ifunanya, ẹni ọdun mejilelogun ka yoo lo l'ọgba ẹwọn lori ẹsun jibiti owo ti wọn l'oun at'awọn ọrẹ ẹ jọ lu

Awọn ọrẹ rẹ naa ni Kingsley Omenazu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Okorie Kosalachi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti wọn f'ẹsun jibiti ori ayelujara ti i ṣe Yahoo-Yahoo kan.

Ọjọ Tuside ijẹta l'ajọ EFCC f'oju awọn eeyan naa ba ile-ẹjọ giga to wa niluu Enugu. 

Onidajọ n'igba to n gbe idajọ kalẹ sọ pe aaye ṣi silẹ f'awọn eeyan yii lati san owo itanran ti ko din ni miliọnu meji naira dipo ki wọn lọ ọ lo ẹwọn ọdun meji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI