AWUJALẸ DI ALAGA IGBIMỌ LỌBA-LỌBA N'IPINLẸ OGUN, NI DAPỌ ABIỌDUN BA KILỌ F'AWỌN ỌBA LORI AMỌTẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 27, 2020

AWUJALẸ DI ALAGA IGBIMỌ LỌBA-LỌBA N'IPINLẸ OGUN, NI DAPỌ ABIỌDUN BA KILỌ F'AWỌN ỌBA LORI AMỌTẸKUN

Gọmina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti gba awọn ọba lamọran wi pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu eto aabo ilẹ Yoruba, iyẹn Amọtẹkun lati le jẹ ki eto aabo ẹmi ati dukia araalu f'ẹsẹ mulẹ daadaa.
Ọjọru ti i ṣe Wẹside ana ni gomina Abiọdun sọrọ yii ni Aafin Awujalẹ tilẹ Ijẹbu to wa n'ilu Ijẹbu-Ode, iyẹn nibi ti wọn ti yan Ọba Sikirulai Kayọde Adetọna gẹgẹ bi alaga igbimọ awọn ọba n'ipinlẹ naa.
 
N'ibẹ ni Abiọdun ti sọ pe ki i ṣe pe awọn gomina ilẹ Yoruba dee de gbe eto aabo Amọtẹkun kalẹ, bi ko ṣe lati fi koju awọn iṣoro to n koju awọn ọmọ Yoruba lori eto aabo bi i ijinigbe, ipaniyan, idigunjale at'awọn oniiru iwa buruku mi-in.
 
Dapọ Abiọdun l'awọn iṣoro yii n fa ọwọ idagbasoke eto ọrọ aje sẹyin pupọ kaakiri ilẹ Yoruba. 
 
O ṣapejuwe awọn ọba gẹgẹ bi awokọṣe lori eto aabo, to si l'awọn gan an ni wọn le jẹ ki eto naa l'aṣeyọri, n'ipa sisunmọ awọn eeyan to wa lagbegbe wọn.
 
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Sikirulai Adetọna dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun at'awọn ọba kaakiri ipinlẹ Ogun fun ifọwọsowọpọ wọn lati yan an gẹgẹ bi alaga igbimọ lọbalọba, to si ṣeleri wi pe oun yoo sa ipa oun lati tubọ mu idagbasoke ba ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI