ẸGBẸ OṢELU PDP KỌJU IJA SI BUHARI LORI IṢẸLẸ CORONAVIRUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 29, 2020

ẸGBẸ OṢELU PDP KỌJU IJA SI BUHARI LORI IṢẸLẸ CORONAVIRUS

Ẹgbẹ oṣelu alatako nni, Peoples Democratic Party (PDP) ti sọ pe aikun oju oṣuwọn to lo n da ijọba orilẹ-ede yii labẹ Muhammadu Buhari laamu, ati pe ailakasi awọn eeyan lo jẹ ko k'awọn mọra lati gba aarun aṣekupani naa wọle si Naijiria.

O ni tori pe ẹmi ati dukia awọn araalu ko jẹ ijọba logun la fa a ti wọn fi f'ọwọ yọbọkẹ mu eto ilera, paapaa lati tete wa ọna lati gbogun ti aarun naa ko to o wọle.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọdiyan fi sita lo ti sọ pe ijọba Buhari ko si laaye s'awọn ojuṣe rẹ, ti wọn si kọ lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe lati dẹkun aarun yii ko to o wọ Naijiria, to si n dẹruba awọn eeyan.

O ni ijọba to ba mọ ohun to n ṣe yẹ ko ti bẹrẹ igbesẹ lati wa ni imurasilẹ, ki wọn si ti mọ pe igbakugba ni aarun naa le wọle wa, ṣugbọn tori wọn ko ni imọ nipa nnkan to n jẹ ijọba lo jẹ ki wọn maa wa iroyin ẹlẹjẹ kaakiri.

Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ rẹ wi pe titi di asiko yii ni ijọba Buhari ko ti i gbe igbesẹ lati ṣe iranwọ to yẹ f'awọn ọmọ Naijiria to wa lorilẹ-ede China pẹlu bi wọn ṣe n fojoojumọ bẹbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI