NKAN DE! WỌN TI ILEEṢẸ LAFARGE EWEKORO PA N'ITORI AARUN CORONAVIRUS, L'AMUGBALẸGBẸ BUHARI BA K'ỌJU IJA S'AWỌN AṢOFIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 29, 2020

NKAN DE! WỌN TI ILEEṢẸ LAFARGE EWEKORO PA N'ITORI AARUN CORONAVIRUS, L'AMUGBALẸGBẸ BUHARI BA K'ỌJU IJA S'AWỌN AṢOFIN

L'ọjọ Fraide ana ni ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn ti ri eeyan mejidinlọgbọn ti ni ajọṣepọ pẹlu oyinbo ọmọ orilẹ-ede Italy to jẹ oludamọran pataki (consultant) fun ileeṣẹ Lafarge to n ṣe simẹnti n'ilu Ewekoro, ipinlẹ naa laarin ọsẹ yii, iyẹn latigba to ti wọ Naijiria.

Gomina Dapọ Abiọdun sọrọ yii n'ibi ipade awọn oniroyin to ṣe lati f'idi ẹ mulẹ wi pe aarun aṣekupani ti Coronavirus to n tan kaakiri agbaye ti wa ni Naijiria, ṣugbọn ti igbesẹ ti n lọ lati tete dẹkun rẹ ko to o tun tan kaakiri.

AWIKONKO gbọ pe papakọ ofurufu Murtala Mohammade to wa n'Ikẹja, Eko ni ọkunrin ti a ko ti i mọ orukọ rẹ titi d'asiko yii naa wọle si Naijiria l'ọjọ Mọnde, to si lo ọjọ mẹta gbako ko to o lọ silu Ewekoro lati b'awọn alakoso ileeṣẹ Lafarge ṣe ipade.

Ibi ipade naa la gbọ pe ọkunrin yii di dubulẹ aisan, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu ileeṣẹ Lafarge, ṣugbọn n'igba ti wọn ri i pe agbara wọn ko fẹ ẹ ka a lo mu ki wọn tete gbe e lọ si ọsibitu LUTH, iyẹn Lagos State University Teaching Hospital n'ibi to ti n gba itọju lọwọ.

Ijọba ipinlẹ Eko n'igba t'iroyin naa ti jade wi pe aarun naa ti wọ Naijiria, ni wọn ti bẹrẹ si i ṣe iwadii awọn ti ọkunrin naa ti ni ajọṣepọ pẹlu laarin asiko to fi wa n'ipinlẹ naa, ko to o wa s'ipinlẹ Ogun.

Gomina Abiọdun ninu ọrọ rẹ sọ pe "Ileeṣẹ ti a sọrọ nipa ẹ yii, iyẹn ileeṣẹ ti ọkunrin naa ti wa a ba wọn ṣe ipade lati ti paṣẹ pe ki wọn ti pa fun igba diẹ, ti a si tun ṣe pese aaye meji ọtọọtọ t'awọn eeyan yoo farapamọ si (isolation centres).

"Wọn ti tọka awọn ti ọkunrin naa laṣepọ pẹlu, ti gbogbo wọn si jẹ mejidinlọgbọn (28), ti igbesẹ si ti n lọ lori wọn"

Ṣaaju asiko yii ni Kọmiṣanna f'eto ilera, Dọkita Tomi Coker fi f'idi rẹ mulẹ pe ọmọdun mẹrinlelogoji (44) ni ọkunrin ọmọ bibi orilẹ-ede Italy naa, to si jẹ aarin wakati mejila l'awọn fi gburo iṣẹlẹ Coronavirus.

Tomi Coker sọ pe lẹsẹkẹsẹ l'awọn ti pese awọn ẹrọ ibanisọrọ ara-ọtọ silẹ f'awọn araalu lati pe bi wọn ba kofiri aarun yii lara awọn eeyan, ki igbesẹ le tete wa ko too pẹ ju. Awọn nọmba naani: 08188978392, 08188978393.


Ninu iroyin mi-in to farapẹ ẹ amugbalẹgbẹ Aarẹ lori ọrọ iroyin ayelujara (Special Assistant to the President on New Media), Tolu Ogunlesi ti bu ẹnu atẹ lu ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede yii wi pe ko si awọn ẹrọ ayewo l'awọn papakọ ofurufu Naijiria.

Ọjọbọ ti i ṣe Tọside ni Ogunlesi pariwo sita lori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ.

O ni ṣe lo yẹ k'awọn aṣofin naa ti ranṣẹ si ileeṣẹ eleto ilera apapọ orilẹ-ede yii lati pese awọn ẹrọ ayẹwo s'awọn papakọ ofurufu lati dena aarun yii. O l'oun to le maa jẹ ibinu ni pe k'awọn ti a ro pe wọn l'ọgbọn lori ma ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe lasiko bi i ki wọn ti ke s'awọn ileeṣẹ eleto ilera lati mọ nnkan to n lọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI