ÈTÒ AYẸYẸ ỌDÚN ÌLÙ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ N'IPINLẸ YÓÒ BẸ̀RẸ̀ LAIPẸ - REMMY HAZZAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 24, 2020

ÈTÒ AYẸYẸ ỌDÚN ÌLÙ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ N'IPINLẸ YÓÒ BẸ̀RẸ̀ LAIPẸ - REMMY HAZZAN


Amugbalẹgbẹ Gomina ipinlẹ Ogunlórí ọ̀rọ̀ iroyin, Pasitọ Remmy Hazzan tí sọ pé eto ayẹyẹ ọdún ilẹ̀ Áfríkà t'ijọba ipinlẹ náà máa ń ṣagbatẹru rẹ lọdọọdun yóò bẹ̀rẹ̀ laipẹ.

Remmy Hazzan fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lónìí lásìkò tó ń báwọn akọroyin kan sọ̀rọ̀ n'ilu Abẹ́òkúta, níbi tó ti ń dáhùn oríṣiríṣi ìbéèrè nípa ìjọba ipinlẹ náà àti orilẹ-èdè lapapọ.

O ni kò sí nnkan to dá ìjọba Dapọ Abiọdun dúró láti tẹsíwájú eto naa gẹgẹ bí ìjọba àná ṣe ń ṣe é, àti pé ọ̀nà ara ní ayẹyẹ t'ọdun yìí yóò gbà wáyé.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI