IJO ZANKU: AWỌN NNKAN TO YẸ KI TỌPẸ ALABI MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 24, 2020

IJO ZANKU: AWỌN NNKAN TO YẸ KI TỌPẸ ALABI MỌ

Mo ki ẹyin alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe Iroyin Awikonko jade lori ikanni ayelujara. Mo fẹ ẹ fi da a yin l’oju pe iṣẹ ribiribi ni ẹ n ṣe lati gbe aṣa, iṣe ede Yoruba larugẹ, paapaa lori ayelujara. Mo fẹ ẹ le sọ pe ko ti i si iru ikanni ayelujara to n fi ede Yoruba gbe iroyin jade to le fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ti yin yi i.

O maa wu mi lati ran mi lọwọ ki ẹ le ba mi gbe ọrọ kekere ti mo kọ n’ipa gbajumọ olori ẹmi nni, Ajihinrere Tọpẹ Alabi, ẹni ọpọ awọn eeyan n wo gẹgẹ bi awokọṣe lagboole onigbagbo jade.

Lati ọsẹ meloo kan ni ọrọ ijo ti gbajumọ olorin ẹmi naa ti n ja rain-rain nilẹ, b’awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu ijo Tọpẹ Alabi jo nibi alẹ awọn oṣere isinku Baba rẹ, bẹẹ l’awọn kan sọrọ si Tọpẹ Alabi lori aṣọ ati ṣokoto to wọ, t’awọn mi-in si n sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ. Tọpẹ funra rẹ gba ori ẹrọ amohunmaworan, iyẹn tẹlifiṣan lọ lati sọ wi pe ko si nnkan to buru ninu ijo toun jo ati aṣọ toun wọ. O ni ọna kankan ṣoṣo lati fi pa ironu iku baba oun rẹ kuro l’ọkan oun niyẹn. Beeyan yo o ba jo, ṣe bi i ti ṣokoto ni ati ijo aye ni?

Bi wọn ba n sọ n’ipa ogbontarigi olorin ẹmi n’ilẹ adulawọ ti aye fẹran rẹ jake-jado agbaye, ọkan pataki ni Temitọpẹ Patricia (Ọbayọmi) Alabi jẹ, bi wọn ba si ni ki wọn maa ka awọn olorin ẹmi l’orilẹ-ede Naijiria ti Ọlọrun n lo lati yi igbesi aye awọn alainigbagbọ pada s’ọdọ Jesu to n fi orin rẹ polongo, ki wọn to o darukọ mẹwaa, Tọpẹ Alabi wa laarin marun-un akọkọ, iyẹn bi ko ba si ninu mẹta akọkọ.

Ọpọ awa ti a mọ Tọpẹ Alabi n’igba to bẹrẹ orin kikọ rẹ la mọ pe obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa ko fi bẹ ẹ fẹran iyẹri eti (earing) ati ẹgba ọrun (chain), ko da, ki i saba lo o ninu awọn fọnran orin rẹ to kọkọ gbe jade n’igba naa. Awo orin Tọpẹ Alabi kan to mi gbogbo agbaye titi, to si yi ọpọ aye awọn eeyan si rere.

Ko lonka l’awọn ti wọn jẹri si agbara Ọlọrun ninu awo orin yii ti Tọpẹ Alabi pe akọle rẹ ni Kọkọrọ Igbala to gbe jade l’ọdun 2008, n’ibi to ti tabuku awọn aṣọ iwọkuwọ ati imura ti ko ba ilana Ọlọrun mu. Ninu awo orin yii ni Tọpẹ ti bu ẹnu atẹ lu b’awọn obinrin ṣe n wọ ṣokoto, ti wọn n lo iyẹri eti ati ẹgba ọrun. O sọ atubọtan awọn iwa yii, ati ijiya to wa nibẹ lẹyin aye yii. Tọpẹ Alabi jẹ ko di mimọ pe ko si ani-ani, ọrun apaadi l’awọn ẹlẹṣẹ n lọ.

Gbogbo awọn awo orin Tọpẹ Alabi lo fẹ ẹ jẹ pe ko si eyi ti ko ti waasu ihinrere nibẹ, ti yo o si tun fi ẹsẹ bibeli ṣe apẹẹrẹ f’awọn eeyan lati yipada. Lai fi kun tabi yọ kuro ninu ọrọ bibeli to n kilọ wi pe awọn obinrin ko gbọdọ wọ aṣọ ọkunrin, bẹẹ l’awọn ọkunrin ko gbọdọ mura obinrin, tọpẹ funra rẹ mọ, to si fi n waasu.

Ko si onigbagbọ to mọ nnkan to gba daadaa, to maa ri ijo olorin aye nni, Zantu, Gbẹsẹ ti tọpẹ Alabi jo, ti ko ni i mọ pe eṣu ti n lo obinrin naa gidi bayii. O ti pẹ t’awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti n kilọ fun Tọpẹ Alabi wi pe igbesi aye rẹ ti yi pada patapata kuro l’ọdọ Jesu, ti wọn si n ki i nilọ wi pe ko tete ṣe atunṣe.

O maa n jẹ ohun iyalẹnu wi pe b’awọn ojiṣẹ Ọlọrun ba n gba Tọpẹ lamọran lori awọn iwa ti ko ba ilana Ọlọrun to n hu, paapaa n’ipa imura rẹ, pupọ awọn ololufẹ Tọpẹ Alabi ni wọn maa n pe awọn ojiṣẹ ọlọrun bẹẹ ni iranṣẹ eṣu, ati pe ki Tọpẹ ma wo ọdọ wọn.

Ibanujẹ lo maa n jẹ wi pe awọn eekanna ti Tọpẹ Alabi n lẹ mọ ọwọ to irinṣẹ f’awọn birikila ti wọn ba fẹ ẹ gbẹn ilẹ fandeṣan (foundation) ile, bẹẹ ni irun oju rẹ tun gun bi irun oju inọki. Awọn imura ti ko yẹ ki Tọpẹ maa mu lo fi n ṣe ayọ yọ, to si n sọ pe ko s’ohun to buru nibẹ. Ṣe bẹẹ naa lo ri? Otitọ ọrọ koro loootọ, ṣugbọn awọn to ba n’ifẹ eeyan lo n gba ‘ni lamọran.

Mo ranti daadaa wi pe l’ọdun to kọja, Wolii kan, Wolii Victor Edet l’ọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 2019 to kọja lo gba Tọpẹ Alabi lamọran wi pe ko ṣọra f’awọn iwa rẹ lasiko yii, paapaa imura rẹ, to ri pe ko ba ilana Ọlọrun ati ọrun rere to n fọnrere rẹ kaakiri. Wolii naa jẹ ko di mimọ pe ọrun apaadi n run lori Tọpẹ Alabi gidigidi, ti Iroyin Awikonko naa si gbe e wi pe Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ N RÙN L'ÓRÍ TỌ́PẸ́ ÀLÀBÍ - AJÍHÌNRERE VICTOR EDET PARIWO SÍTA

Buọda Sọji Alabi to jẹ ọkọ anti Tọpẹ naa pariwo sita wi pe k’awọn eeyan fi iyawo oun silẹ, ki wọn ran ti wọn, o ni k’awọn to n sọrọ iyawo oun gbe ẹru ẹlẹru kuro lori, ki wọn si gbajumọ ti wọn. Ṣugbọn ohun ti t’ọkọ t’iyawo yii ko mọ ni pe awokọṣe ni wọn jẹ lagboole onigbagbọ, t’awọn alaigbagbọ si n yi pada pẹlu iṣẹ ti ori fi ran wọn.

Ko sẹni to korira Tọpẹ Alabi, bẹẹ si ni ko sẹni ti ko n’ifẹ rẹ, awọn ti n wọn n bu ẹnu atẹ lu ijo aye ti Tọpẹ Alabi jo lọsẹ meji sẹyin yii ni wọn fẹran rẹ, ti wọn ko si fẹ ko parun lojiji, tori pe ọpọ aye awọn eeyan lo ti yipada si rere. Wọn si gbọdọ mọ wi pe gbogbo awọn ti wọn n gbeja Tọpẹ ni wọn ko fẹran rẹ, ‘aṣiwere to n wa ẹni kunra’ ni wọn. Wọn fẹ ki Tọpẹ naa darapọ mọ wọn lati le maa ri ohun kan tabi omi-in sọ.

Tọpẹ ni lati tun bibeli rẹ gbe yẹwo daadaa, ko si ṣe awọn atunṣe to ba yẹ ko to o pẹ ju. Loootọ ni ko si ẹni to pe, ko da, emi ti mo n kọ ọrọ yii, ẹlẹṣẹ ni emi naa, ti mo si n wo Tọpẹ gẹgẹ bi awokọṣe lagboole onigbagbọ. Ọpọ imura onigbagbọ lo wa, bẹẹ ni ọpọ ijo onigbagbọ lo wa. Mi o fẹẹ sọrọ pupọ.


Lati Ọwọ 'Gbenro Adetunji Akinosi

2 comments:

  1. Dadi wa, mo fe gba yin ni imoran wi pe kí e di ìgbàgbọ yín mu danhin dahun lo ṣe pàtàkì jù lo. Eyi Ey ni o yẹ ki o je iwasu yín fún àwọn Onigbagbo. Oro Ajinhinrere Tope Alabi ti e tẹ pẹpẹ rẹ yi ni opolopo iho ninu ti o sí sì lè fa àríyànjiyàn, eyi ti Bíbélì kìlọ̀ pe ki a y'era fún.

    Ní àkọ́kọ́ na, ṣòkòtò ọkùnrin yàtọ̀ gedegbe sí ti obinrin. Bí ẹ ba ní anfààní lati rin irin ajo lọ sí òkè òkun, oun tí m'oun wí yóò yé yin dáadáa. Ní ìlú Nàìjíríà, at'ile ni àwọn ẹyà nibi ti ọkùnrin tí n ro iro (Awọn Ijaw). Imura ni pupo se pèlú àṣà, kii se pèlú ẹ̀sìn rara. Nipa ti ijó yen, emi ko mo pupo nipa re. Nítorí náà, mi o ni s'oro nípa rẹ̀.

    Kí Olúwa túbò máa fi òye ọrọ rẹ ye wa (Amin)

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI