IDI TI MO ṢE SA KURO N'ILE ỌKỌ L'ẸYIN ỌDUN KAN ATI OṢU MẸRIN TI A ṢE'GBEYAWO - BIMBỌ, GBAJUMỌ OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, February 1, 2020

IDI TI MO ṢE SA KURO N'ILE ỌKỌ L'ẸYIN ỌDUN KAN ATI OṢU MẸRIN TI A ṢE'GBEYAWO - BIMBỌ, GBAJUMỌ OṢERE TIATA

Ilu mọ-ọn ka oṣere tiata nni, Bimbọ Akinsanya ti pariwo sita wi pe ka ni oun ko tete sa kuro n'ile ọkọ oun l'ẹyin igbeyawo ni, o ṣee ṣe k'oun ti ku, ati pe to ri oun ṣi fẹẹ wa l'aye lo jẹ k'oun gbe igbesẹ naa, bo tilẹ jẹ pe o ni ko rọrun.

Bimbọ Akinsanya s'ọrọ yii l'asiko to n bu ẹnu atẹ lu Maryam Sanda ti ile ẹjọ da ẹjọ iku fun l'ori bo ṣe gun ọkọ rẹ Bilyaminu Bello pa.

O ni “Mo sa kuro n'ile ọkọ mi ni kete ti ọmọ ti mo bi pe oṣu mẹta gbako. Ṣe ẹ ro pe o rọrun bẹẹ lati gbe iru igbesẹ bayii ni? Rara o, ko r'ọrun fun mi. Mo tete fi ile ọkọ mi s'ilẹ nitori pe mi o fẹẹ ku.

"Mo tete sa kuro nibẹ nitori pe mi o fẹẹ padanu ọmọ mi, mo tete sa jade kuro nibẹ nitori pe mi o fẹẹ di apaayan. (ki i ṣe itan asiko yii, igba mi-in ni.)

"Ọdun kan ati oṣu mẹrin pere ni mo fi gbe n'ile ọkọ mi, iyẹni ninu igbeyawo mi, to si jẹ pe bi ọrun apaadi lo ri. Ẹ gbọ mi, ẹ ma ṣe ọmọ ọlọmọ nitori ọrọ igbeyawo. Iya l'emi naa, mo si mọ bi mo ṣe n ṣe wahala lati kọ ọmọ mi, ki n tooo fun un l'ounjẹ.

"Ẹ jọwọ, ẹ ma ṣe gbadura tabi ki ẹ ro ero buruku wi pe ki obinrin ṣe laala l'asan, ko si ma jeere ọmọ rẹ."

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI