TOYỌ BABY NINU FIIMU JẸNIFA BU S'ẸKUN N'ITA GBANGBA PẸLU BỌMBU ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 1, 2020

TOYỌ BABY NINU FIIMU JẸNIFA BU S'ẸKUN N'ITA GBANGBA PẸLU BỌMBU ỌRỌ

Ọpọ awọn to gbọ ọrọ ti gbajugbaja oṣerebinrin nni, Juliana Ọlayọde sọ n'ipa b'awọn eeyan ṣe maa n mọ riri awọn gbajumọ l'ẹyin ti wọn ba ku tan, ti ko ni i mọ pe inu rẹ ko dun rara l'asiko yii, to si jẹ pe pẹlu omije oju lo fi n s'ọrọ naa.

Juliana ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Toyọ Baby ninu fiimu atigbadegba kan, Jẹnifa's Dairy ti Funkẹ Akidele ṣe lo s'ọrọ naa pẹlu ẹdun ọkan n'igba to ri b'awọn eeyan ṣe n pokiki Kobe Bryant to ku l'ọsẹ to kọja yii.

O ni nnkan ti ko ba ti dara julọ ni k'awọn ololufẹ awọn gbajumọ maa gbe oṣuba ati imọriri fun wọn n'igba ti wọn ba wa l'aye dipo bi wọn ba ku tan, to si ni eyi yoo tubọ maa mu ori wọn hu l'asiko ti wọn ba wa l'aye lati tubọ le tẹra mọ awọn nnkan ti wọn mọ-ọn ṣe.


Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “O dabi ẹni pe awọn eeyan maa n ri ifẹ to pọ, wọn si maa ri okiki rere, paapaa wọn maa  ri oṣuba ranbandẹ gba n'igba ti wọn ba ku ju igba ti wọn ba wa l'aye lọ, eyi si jẹ ohun to ba n ba mi l'ọkan jẹ pupọ, to si n da mi lori ru ni gbogbo igba.


“L'ojiji gbogbo eeyan a bẹrẹ si i mọ eni naa, ti wọn si maa gbe fọto rẹ s'ita pẹlu oriṣiriṣi ọrọ adidun, eyi ti wọn ko kọ n'igba aye ẹni naa, paapaa n'igba ti ẹni naa yẹ ko ri i, ko si ka a.


“Ẹ jẹ ka maa fi imọriri han s'awọn ti a ba n'ifẹ si n'igba ti wọn ba wa l'aye, ati l'asiko ti wọn le ri i, ki wọn si le mọ bi wọn ṣe ri l'ọkan wa, nitori pe bi wọn ba ku tan, wọn ko mọ ohun ton ṣẹlẹ mọ, wọn ko si ni i l'anfaani lati ri awọn ọrọ adidun ati ikẹdun ti a ba gbe s'ori ikanni ayelujara n'ipa wọn, bẹẹ ni wọn ko ni i gbọ ohun t'awọn eeyan n sọ mọ n'ipa wọn, ati pe wọn ko tun ni mọ bi wọn ṣe mu inu wọn dun ati ipa ti wọn ko n'igbesi aye wọn.



“Asiko naa re e lati ṣe e; ẹ jẹ ka maa ba wọn yọ l'ọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi wọn, n'igba ti wọn ba n ṣe oniruuru ayẹyẹ ati aṣeyọri, ẹ duro ti wọn n'igba ti wọn ba kuna, ẹ jẹ ki wọn mọ bi wọn ṣe ṣe pataki to l'ọkan yin.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI