ÌYÀWÓ YA WÈRÈ LỌ́JỌ́ ÌGBÉYÀWÓ RẸ̀ L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, February 20, 2020

ÌYÀWÓ YA WÈRÈ LỌ́JỌ́ ÌGBÉYÀWÓ RẸ̀ L'EKITI


Ṣé ni ọrọ di pẹntuka lọsẹ tó kọjá yìí nígbà tí wón ní obìnrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Rachael Abimbọla yà wèrè níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó rẹ.

Ìpínlẹ̀ Ekiti là gbọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé, nígbà tí wón ní àsìkò tó kú díẹ̀ kí Rachael gba òrùka lọ́wọ́ ọkọ rẹ tuntun tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ tá a fi kọ ìròyìn yìí tán. 

A gbọ pé ọkùnrin kan tí wọn pé orúkọ ẹ ní Samson Ọlọlade  lòun àti Rachael jọ ń ṣe wọlé-wọ̀de n'ipinlẹ Edo tó ń gbé tẹ́lẹ̀, kò dá tí wọn sọ pé àwọn méjèèjì tí mú ọjọ́ ìgbéyàwó. 

A gbọ pé miliọnu méjì dín ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọọdunrun (1.7m) náírà ni Rachael tí gba lọ́wọ́ Samson nígbà tí ọjọ́ ìgbéyàwó tí wọn dá kú oṣù mẹ́ta gbáko. 

Ṣádede ni wọn sọ pé Rachael ba ọkùnrin mi ín pàdé n'ilu Ọtun Ekiti, tó sì wá gbogbo ọ̀nà láti bá Samson ja, kí wọn lé tuka. N'igba tí wọn ní àárín àwọn méjèèjì dàrú pátápátá ní Samson bẹ̀rẹ̀ sii béèrè owó ẹ padà, ṣùgbọ́n tí wọn ní Rachael sọ pé ìdí tí jẹ, jọ sí lè ríi gba padà mọ. 

Gbogbo akitiyan Samson láti gba owó rẹ padà lọ́wọ́ Rachael ni wọn loo ja si pàbó, kò too di pé ó fi silẹ. 

Àbúrò Rachael, ìyẹn Bọlanle tó tú àṣírí náà síta sọ pé àwọn bẹ Rachael láti dá owó olówó padà, ṣùgbọ́n tí kò gbọ.

Asiko ti wọn ni Rachael fẹẹ gba òrùka là gbọ pé ọ̀rọ̀ rẹ bẹ̀rẹ̀ sii tase, t'awọn èèyàn sì ro pe ojú lásán ni. Kò pé tí wọn ní Rachael bẹ̀rẹ̀ sii bọ aṣọ rẹ, kò too di pé wọn muu. 

Ọsibitu tí wọn tí ń tọju àwọn alaaganna, Psychiatric là gbọ pé Rachael wá títí tá a fi kọ ìròyìn yìí tán.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn kan ń sọ ní pe Samson yóò mọ nípa nnkan tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n táwọn kan ń sọ pé afọwọfa lásán ni, ati pe o ṣeé ṣe kí Samson má mọ nípa rẹ rárá.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI