KO SẸNI TO TO BẸẸ LATI RỌ MI L'ỌBA - OLUWO JU BỌMBU ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 21, 2020

KO SẸNI TO TO BẸẸ LATI RỌ MI L'ỌBA - OLUWO JU BỌMBU ỌRỌ

Oluwo tilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti fesi lori ipinnu igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọṣun to ni ko lọ rọọkun ile fun oṣù mẹfa gbako.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwo ni loootọ ni awọn ṣe ipade lọbalọba loootọ ti Ọọni ko si ni aṣẹ lati ni ki oun lọ rọọkun ile na.

O ni gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Gboyega Oyetọla nikan lo ni àṣẹ lati ni ki oun lọ rọọkun ile na, to si dabi ẹni pe wọn ti ni nnkan ninu si oun.


"O dabi ẹni pe inu wọn ko dun bi mo ṣe maa n ṣakọ, ti wọn si n binu mi. Gbogbo wọn ni wọn kan ọ̀rọ̀ mi sinu, o si dabi ẹni pe ọta pọ, Ọlọrun yoo si gbe mi bori wọn."

Nigba to n sọrọ lori bi wọn se ni o yaju si Alaafin ati Ọọni, Oluwo ni oun ko gba ade ni Ọyọ, oun si ni oun laṣẹ lati fi ọba miiran jẹ nilẹ Iwo, kii se Alaafin, gẹgẹ bo ṣe waye ni Ikoyi.


"Ile Ifẹ ni mo ti gbade l'ọdọ iya mi, tori ọmọ alade ni mi n'ile Ifẹ, emi ko gba ade ni Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ni Alaafin wa, ko si le maa gbe ade le Onikoyi to wa l'abẹ mi lori. Alaafin sọrọ si mi tori pe n ko jẹ ko gbe ade le Onikoyi lori, amọ ibi to ba kan onikaluku ni ko duro si bii ọba."

Oluwo ni oun ṣi ni Ọba alade nilẹ Iwo, Oluwo ti Iwo, Alase lori òrìṣà, ọba miiran ko si le ni ki oun lọ rọọkun ile na, wọn kan le ni ki oun ma wa si ipade wọn mọ ni.

Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l'Ọ́ṣun ní kí Oluwo lọ rọ́ọ́kún ílé fún oṣù mẹ́fà
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti kede pe igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọṣun ti ni ki Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi lọ rọọkun ile fun osu mẹfa gbako.

Igbimọ kan ti igbimọ lọbalọba naa gbe kalẹ, eyi ti Ọrangun ile Ila, Ọba Wahab Adedọtun jẹ adari rẹ lati sewadi awọn isẹlẹ to nii ṣe pẹlu Oluwo, gbe abọ wọn kalẹ lọjọ Ẹti, ìyẹn Fraide onii.

Lẹyin abọ igbimọ naa, ni igbimọ lọbalọba ọhun pe ipade pajawiri, eyi to waye nibujokoo ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa ni Abẹrẹ.

Ipade naa, ti Ọọni t'ilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi lewaju rẹ, wa fohun ṣọkan pe ki Oluwo lọ rọọkun ile na fun oṣù mẹfa gbako.

Igbesẹ yii si lo waye lẹyin ọsẹ kan pere ti Oluwo lu Agbowu tilu Ọgbaagba nibi ipade alaafia kan ti igbakeji ọga agba ọlọpaa pe n'ilu Oṣogbo.

Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade pajawiri naa, Ọrangun Ile Ila ni àṣẹ ti igbimọ naa pa pe ki Oluwo lọ rọọkun ile na ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ija to waye laarin rẹ ati Oluwo.

Amọ sá, o ni wọn ṣe ipinnu ọhun lẹyin ìwádìí wọn nipa iṣesi Oluwo si awọn ọba alaye yooku n'ilẹ Yoruba.

Ọrangun ni Oluwo ti yaju tẹlẹ si Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta ati Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi.

Lati BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI