O PARI! LYON GBA KAMU LORI IDAJỌ ILE-ẸJỌ AGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, February 29, 2020

O PARI! LYON GBA KAMU LORI IDAJỌ ILE-ẸJỌ AGBA

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC ti wọn dibo yan n'ipinlẹ Bayelsa, ṣugbọn ti ile-ẹjọ agba le danu lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan igbakeji rẹ, David Lyon ti sọ pe oun ti gba kamu, oun si ti gba kadara lori idajọ ile-ẹjọ giga to le oun danu laipẹ yii.

L'ọjọ Wẹside to kọja yii ni igbimọ ẹlẹni meje ti ile-ẹjọ agba orilẹ-ede yii, iyẹn Supreme ti Onidajọ Sylvester Ngwuta lewaju rẹ ti da ẹjọ kotẹmilọrun ti Lyon pe lori idajọ to le e danu kuro n'ipo ti wọn dibo yan an si.

Igbakeji Lyon, Biobarakuma Degi-Eremienyo la gbọ pe orukọ ọtọọtọ lo n lo lati kekere, to fi jade ileewe girama, ileewe giga, titi to fi gbe apoti ibo, to si jẹ ṣe lo n paarọ orukọ bi ẹni to paarọ aṣọ.

Lyon sọ pe oun ti gba kamu ninu atẹjade to fi sita l'ọjọ Tọside ijẹta yii wi pe k'awon gbagbe gbogbo nnkan to ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun, k'awọn si duro lori aṣẹ ile ẹjọ agba.

O l'oun nigbagbọ wi pe Ọlọrun n'ifẹ gbogbo awọn ọmọ Baylesa, ti yoo si tun pada mu ileri rẹ ṣẹ fun wọn, fun idi eyi, o ni ki wọn yago fun ohun gbogbo to le da wahala silẹ n'ilu, ki wọn si wa ni iṣọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI