ỌBA KAN ṢOṢO TI MO B'ỌWỌ FUN N'ILẸ YORUBA - OLUWO TUN JU BỌMBU ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, February 24, 2020

ỌBA KAN ṢOṢO TI MO B'ỌWỌ FUN N'ILẸ YORUBA - OLUWO TUN JU BỌMBU ỌRỌ


Ọba Abdulrọṣheed Adewale Akanbi tun ti ọrọ mi in sita wi pe ki i ṣe gbogbo ọba l'oun le maa bọwọ fun, nitori pe awọn kan ko tọ si ọwọ, to si ni l'ara awọn ọba t'oun maa n b'ọwọ fun ni Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ.

F'awọn to ba mọ Oluwo daadaa, wọn a mọ pe ko fẹ ẹ si ọba alaye kan ti ko ti i bu ẹnu atẹ lu n'ilẹ Yoruba, paapaa n'ipinlẹ Ọṣun, to si maa n f'oju gbolẹ gidigidi.

Oju opo Instagram ni Oluwo ti sọrọ naa l'opin ọsẹ to kọja yii, to si tun gbe fọto oun pẹlu Alake sita lati jẹ k'awọn eeyan mọ pe oun mọ Alake ilẹ Ẹgba daadaa.

Oluwo jẹ ko ye awọn eeyan wi pe Alake n'ikan ni ọba to maa n fi ara rẹ s'ipo, ti ki i si i kọja aaye ẹ kaakiri bi i t'awọn ọba yooku.
 

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI