ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ FULANI DARAN-DARAN MẸWAA L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, February 24, 2020

ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ FULANI DARAN-DARAN MẸWAA L'EKITI

L'ọjọbọ ti i ṣe Tọside ọsẹ to kọja yii l'ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti tẹ awọn Fulani Daran-daran ti ko din ni mẹwaa ti wọn f'ẹsun kan wi pe ibọn ni wọn n ko kaakiri gbogbo ilu Emurẹ-Ekiti n'ipinlẹ naa lati fi dẹru b'awọn eeyan.

A gbọ pe ọsan gangan l'awọn Fulani yii wọ ilu naa pẹlu ibọn nla-nla lọwọ, to si mu ki ẹru maa ba awọn araalu naa.

Oju ti wọn l'awọn araalu ko ri ri l'awọn Fulani yii, eyi lo fa a ti wọn l'awọn eeyan fi ranṣẹ s'awọn ọlọpaa lati wa a wo wọn, ki wọn si ko wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko ti i le sọ boya ọdaran ni wọn, ṣugbọn to ni loootọ l'awọn gba ibọn lọwọ wọn.

O ni b'awọn ṣe ri wọn, oju ọlọdẹ l'awọn fi wo wọn, paapaa nitori awọn ibọn ti wọn gbe dani, to si l'oun yoo jẹ ka mọ b'awọn ba ti ṣewadii daadaa lori wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI