OGBONTARIGI SỌRỌSỌRỌ, ALAWIYE FEDERATION FẸẸ Ṣ'AYẸYẸ ON'IBẸTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 3, 2020

OGBONTARIGI SỌRỌSỌRỌ, ALAWIYE FEDERATION FẸẸ Ṣ'AYẸYẸ ON'IBẸTA


Gbogbo eto lo tí fẹẹ parí báyìí fún ayẹyẹ onibẹta tí gbajugbaja sọrọsọrọ orí redio nnì, Kọmureedi Akinyẹmi Titus Ọlatoye fẹẹ ṣe nínú oṣù kẹta sì oṣù kẹrin ọdún yìí n'ilu Abẹ́òkúta.

Ọsẹ kan gbáko là gbọ pé Akinyẹmi Ọlatoye t'ọpọ àwọn olólùfẹ́ ẹ mọ sì Alawiye Fẹdireṣan (Federation) fẹẹ fi ṣe ayẹyẹ yìí, nítorí tá a gbo pe bo ṣe fẹẹ ṣ'ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún marundinlaadọta (45years) náà lo tún fẹẹ ṣe ayẹyẹ ogun ọdún tó ti ń sọ̀rọ̀ lórí afẹ́fẹ́.


Ìyẹn nìkan tún kọ, a gbọ pé Alawiye to kọ ìṣẹ́ lábẹ́ Olóògbé Tọba Ọpalẹyẹ tún fẹẹ fi ayẹyẹ yìí kò kasẹẹti eto kan tó ń ṣe lórí redio, èyí tó pé ní Láwùjọ Akọni jáde, tá a sì gbọ pé kò dín ni akọni ogún t'ọkunrin náà tí kò jọ.

AWIKONKO tún gbọ pé aṣọ àti fìlà ni yóò jẹ tikẹẹti t'áwọn èèyàn yóò fi wọlé sínú gbọngan ayẹyẹ DLK tó wà lopopona Abiọla Way, Lẹmẹ n'ilu Abẹ́òkúta lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹrin tí wọn yóò kasẹ ayẹyẹ náà n'ilẹ. 


L'ara àwọn ètò tí wọn tí là kalẹ fún ayẹyẹ náà ni abẹwo silẹ àwọn ọmọ alailobii, èyí tí yóò wáyé lọ́jọ́ Aje Mọnde ọgbọ́n ọjọ́ oṣù kẹta; Idanilẹkọọ tí yóò wáyé lọ́jọ́ Iṣẹgun Tuside ọjọ́ kọkanlelọgbọn; Ìyìn àti idupẹ lọ́jọ́ kinni oṣù kẹrin; idije bọọlu àti ifilọlẹ kasẹẹti Láwùjọ Akọni lọ́jọ́ kejì oṣù kẹrin; Ọjọ́ ayẹyẹ tí wẹjẹ wẹmu yóò ti waye; ọjọ́ Sande tí wọn yóò parí gbogbo ẹ ní wọn yóò máa fi dúpẹ́ nílé ìjọsìn African Church tó wà ní Lẹmẹ. 

Àwọn àgbààgbà láwùjọ amuludun bíi Oloye Ebenezer Obey Fabiyi, Ọmọwe Ṣẹfiu Àlàó,. Ambrose Ṣomide, Ọmọba Dele Odule àtàwọn mi-in ni wọn yóò wá nibẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI