ỌRỌ NLA! PASITỌ FẸẸ LỌO ṢIṢẸ ITUSILẸ, LO BA KU SI OTẸẸLI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 24, 2020

ỌRỌ NLA! PASITỌ FẸẸ LỌO ṢIṢẸ ITUSILẸ, LO BA KU SI OTẸẸLI

Gbogbo awọn oṣiṣẹ otẹẹli kan ti a f'orukọ bọ laṣiri ladugbo Onuorah to wa ni abule Amaenyi village, Awka, ipinlẹ Anambra lọrọ iku Pasitọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Richard Ifeanyi Obi ṣi n ya lẹnu.

Ki i ṣe awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa nikan lọrọ iku Pasitọ yii n ya lẹnu, ọpọ awọn to gbọ ni wọn n pariwo 'Jesus is Lord' titi di asiko ti a fi pari iroyin yii.

AWIKONKO gbọ pe idile kan lo ranṣẹ pe Pasitọ Obi lati wa a gbadura itusilẹ fun wọn l'ọjọ Fraide ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn ti wọn ni ọjọ Tọside ni ko ti de, ati pe awọn yoo gba otẹẹli fun un.

Ko pẹ ti Pasitọ naa de otẹẹli yii laarọ Ọjọbọ Tọside naa ni wọn lo o ti bẹrẹ si i gbadura ni imurasilẹ lati lọ ọ ṣiṣẹ itusilẹ f'awọn to pe e l'ọjọ keji.

Lojiji ni wọn sọ pe wọn gbọ ariwo lati inu yara ti Pasitọ Obi wa, ti wọn ko si gbọ ohun rẹ mọ. Aara ti wọn lo o fu awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa n'igba ti wọn ko gbọ ohun rẹ mọ lo jẹ ki wọn lọ sibẹ lati lọ ọ wo o.

Bi wọn ṣe ri ipo ti Pasitọ Obi wa lo mu ki wọn tete ranṣẹ s'awọ ọlọpaa lati wa wo o, t'awọn yẹn naa si sare debẹ.

Pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn fi gbe oku pasitọ Obi lọ si ọsibitu lati ṣayẹwo autopsy, ki wọn le mọ iru iku to pa a.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed to f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ jẹ ko ye wa pe Kọmiṣanna awọn, John Abang ti paṣẹ wi pe ki iwadii tete bẹrẹ lati mọ iru iku to pa Obi, to si ni mọṣuari ọsibitu Amaku ni oku Obi wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI