AYE MA LE O! PAULINA JI IYA ỌRẸ RẸ GBE NITORI OWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, February 24, 2020

AYE MA LE O! PAULINA JI IYA ỌRẸ RẸ GBE NITORI OWO

Abamọ ti wọn lo n gbẹyin ọrọ lo pada gbẹyin iyaale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Paulina Santos ti wọn lo o pinu lati ji iya ọrẹ rẹ timọ-timọ gbe, ko si fi gba obitibiti owo lọwọ ọkọ ọrẹ rẹ t'oun n ṣiṣẹ n'ile epo.

Ipinlẹ Lafia n'iṣẹlẹ naa waye, ti ọga ọlọpaa si f'oju rẹ han sita f'awọn oniroyin lopin ọsẹ to kọja yii.
 
'Ka ni mo mọ pe bi yoo ti ri re e, mi o ba ma ti dawọ le e rara' lọrọ ti wọn lo n tẹnu Paulina ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti wọn lọmọ ijọba ibilẹ Ogbadigbo n'ipinlẹ Benue ni jade.

Ileeṣẹ Nigerian National Petroleum Corporation ni wọn sọ pe ọkọ rẹ Paulina ti n ṣiṣẹ. Oṣu kinni ọdun yii la gbọ pe Paulina pinnu lati ji iya ọrẹ rẹ naa gbe, ti wọn si lo o wa awọn ajinigbe ti yo o ba a ṣiṣẹ naa.

Ọjọ kọkanla oṣu yii laṣiri Paulina to n gbe lagbegbe Azuba Bashayi to wa n'ijọba ibilẹ Lafia North tu s'awọn ọlọpaa lọwọ, to si pada jẹwọ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe ki wọn f'oju aanu wo oun.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI